Gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa fi ọpẹ́ fún Olódùmarè fún ìyanu tó ṣe fún wa. Ní ojoojúmọ́ ni kí a máa fi ọpẹ́ fún- un, kí a sì máa yìn- ín.

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò fún ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Aládé ṣe máa ń sọ fún wa wípé, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé oore ńlá tí Olódùmarè ṣe yí, ní gbogbo ìgbà ni kí a máa fi ẹ̀mí ìmoore wa hàn sí Ọlọ́run Olódùmarè.

Láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a kéde òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ni àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P ti gba agbára àti àṣẹ tí Olódùmarè fún wa gẹ́gẹ́ bí ọmọ Aládé padà. I.Y.P kankan kò tún ṣe ẹrú mọ́. A ò ṣe ẹrú fún àwọn amúnisìn mọ́, a ò ṣe ẹrú olóṣèlú mọ́.

A ti bọ́ lọ́wọ́ amúnisìn, àjẹẹ̀jẹtán ni àwọn àlùmọ́ọ́nì tó wà ní orílẹ̀ èdè wa, ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni yóò wù láti wá máa gbé ní orílẹ̀ èdè D.R.Y nígbà tí wọ́n bá rí ògo wa tó búyọ.

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) nílé àti lẹ́yìn odi, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alákòóso wa, kí gbogbo àwa tí a wà ní ìrìn àjò máa múra láti padà wá sí’lé, kí a leè pawọ́pọ̀ láti tún orílẹ̀ èdè wa ṣe.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wípé àjò kò dà bí ilé, àti pé, ilé làbọ̀ simi oko. Ẹ jẹ́ kí a wá lo ẹ̀bùn ọpọlọ pípé tí Olódùmarè fún wa láti ṣiṣẹ́ fún orílẹ̀ èdè wa kí a lè tẹ̀síwájú. Kí Ọlọ́run Olódùmarè bùkún fún orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates