Akí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) kú oríire fún àṣeyọrí tí Olódùmarè lo màmá wa ìyá ìran Yorùbá Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti ṣe fún ìran Yorùbá.

Ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún Olódùmarè lo màmá wa MOA láti ṣe ìkéde òmìnira wa kúrò nínú ìgbèkùn àwọn amúnisìn àti kúrò lára ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.

A ṣe ìgbà padà ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Ọpẹ́ ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, nínú èyí tí Olódùmarè lo màmá wa MOA láti kọ ìwé sí gbogbo àwọn gómìnà ìlú aríremáṣe Nàìjíríà tí wọ́n ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ Ògùn, ìpínlẹ̀ Oǹdó, ìpínlẹ̀ Èkìtì àti ìpínlẹ̀ old Ọ̀yọ́ Empire, nínú ìwé ọ̀hún, màmá wa jẹ́ kó yé wọn wípé, àwa ọmọ Yorùbá ti ṣe tán láti wá gba ẹ̀tọ́ wa, nítorí náà kí wọ́n kúrò ní orí àga tí wọ́n jókòó sí.

Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kò bọ̀wọ̀ fún òfin, àti pé, wọ́n jọ ara wọn lójú, wọ́n rò wípé kò sí ẹ̀dá náà tó leè ṣí àwọn ní ìdí kúrò lórí ẹ̀tọ́ ọmọ Yorùbà, tí wọ́n ń fipá jẹ gàba lé lórí. Wọ́n bu ọwọ́ lu ìwé ọ̀hún nígbà náà, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n ti buwọ́ lùú pé àwọn ri gbà, wọn ò fèsì títí ọdún kan pé, ó tún lé, èyí tí ó nítumọ̀ lábẹ́ òfin fún ànfààní tiwa.

Olódùmarè gba ẹ̀yìn yọ sí wọn, Ó dojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní alágbára, Ó ṣe àtìlẹ́yìn fún ìran Yorùbá. 

Lẹ́yìn èyí ni a tún ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wa bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn aṣojú wa ní ìpínlẹ̀ méjèèje tó wà ní orílẹ̀ èdè D.R.Y ti wà ní ìkàlẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ loríṣìíríṣìí láti ìgbà náà èyí tí yóò mú ìtẹ̀síwájú àti ìgbéga bá orílẹ̀ èdè D.R.Y. 

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni màmá wa MOA sì ti kọ ìwé sí láti fi tó wọn létí wípé, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti kúrò lára ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, a ti di orílẹ̀ èdè aṣàkóso ara ẹni. 

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), àgbáyé ń retí wa láti bá wa ṣe àjọyọ̀, wọ́n ń dúró láti kí wa kú oríire. 

Ǹjẹ́ a ti ń múra sílẹ̀? Ọjọ́ náà kò ní pẹ́ mọ́ tí àwọn alákòóso wa yóò wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso ní àwọn ìpínlẹ̀ wa. Ẹ jẹ́ kí a máa gbáradì, kí ẹnikẹ́ni má sọ wípé ó bá òun ní òjìji, ìdí nìyí tí a tún fi ń rán ara wa létí wípé, àgbáyé ti ń dúró dè wá láti bá wa yọ, fún ìdí èyí, a tún ń lo àkókò yi láti kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) wípé, a kú oríire.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates