Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ètò ẹ̀yáwó tí kò ní èlé yóò wà fún gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P). Nítorí èyí kí a ma jó kí a sì ma yọ̀.
Nígbà gbogbo ní àwa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P) a ó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó rántí wa sí rere ní déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí tó jẹ́ kí á rí àǹfààní orí ilẹ̀ wa.
Àyípadà rere ti de bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá lọ́wọ́.
Ẹ̀yáwó tí kò ní èlé yóò wà fún gbogbo ọmọ ìbílè Yorùbá tó bá ní ìfẹ́̀ sí. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wọn yí, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀-Èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y)
ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀
Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́. Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.
Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.