Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti jáde kúrò lára Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjì-lé-lógún, bẹ́ẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó-lé-mẹ́rinlélógún, èyí tí ó túmọ̀ sí pé ọ̀ràn-dídá gbáà ni fún Nàìjíríà láti máa ṣe ohunkóhun lórí ilẹ̀ D.R.Y, títí di àkókò yí.
Ìròyìn tí akọròyìn wa kan gbé síta fihàn gbangba pé awa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti D.R.Y níláti tún ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, àti gbogbo agbódegbà wọn, pàápàá àwọn gómìnà Nàìjíríà tí wọ́n ṣì ń fipá dúró sórí ilẹ̀ ọmọ Yorùbá, pé kí wọ́n dẹ́kun àti máa ka Orílẹ̀ èdè wa mọ́ nàìjíríà wọn.
A tún gbọ́ bí ìkan nínú àwọn olóṣèlú Nàìjíríà, Atiku Abubakar, ṣe gbé ohùn síta pé ààrẹ wọn lọ́hun, Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ ìjọba wọn ní nàìjíríà di okòwò ìdílé rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe ní ìpínlẹ̀ Èkó, nígbà tí ó wà ní ipò gómìnà, àti bí Wálé ọmọ rẹ̀ náà ṣe ń ṣe oríṣiríṣi aṣemáṣe ní ìlú wọn Nàìjíríà, ṣùgbọ́n èyí tí ó wá bí wa nínú gẹ́gẹ́bí ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ni bí Atiku ṣe gbẹ́nu lé iṣẹ́ pópónà tí ó pè ní “Lagos-Calabar Coastal Highway;” bẹ́ẹ̀ náà ni ó mẹ́nu lé ìkan tí ó pè ní “Sokoto-Badagry Coastal Highway,” tí ó ní ó wà làra àwọn ibi tí Tinubú àti ọmọ rẹ̀, Wálé, ti ṣe awúrúju gbígbé iṣẹ́ fún agbaṣẹ́ṣe tí ó jẹ́ alábaṣiṣẹ́ ìdílé wọn.
Tinubú àti ìdílé rẹ̀ ìbáà kó gbogbo Nàìjíríà sí àpò wọn kò kàn wá ṣùgbọ́n, ẹ máṣe jẹ́ ká tún gbọ́ orúkọ Èkó (tí ẹ̀yin npè ní Lagos) lẹ́nu yín mọ́, nítorí Èkó kò sí nínú Nàìjíríà, tí ẹ ò bá fẹ́ parẹ́ tìran-tìran; ìwọ Atiku àti gbogbo yín, ẹ ṣọ́ ara yín gidigidi, kí ẹ sì má sọ̀rọ̀ pópónà Sokoto-Badagry kankan mọ́ nítorí pé Orílẹ̀ èdè DRY kìí se ara yín mọ́.
Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á múra gidi, ní gbogbo ọ̀nà tí Olódùmarè bá fún wa ní àǹfààní, láti ri pé a ò gba ìgbàkúgbà láti ọwọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà yí.
Ẹ jẹ́ kí á ránti pé ẹnikẹ́ni ní orí-ilẹ̀ D.R.Y tó bá ṣe àdéhùne pẹ̀lú Nàìjíríà láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ti dá ọ̀ràn lábẹ́ òfin D.R.Y o!
ÌLÚ Èkó kò sí nínú Nàìjíríà bẹ́ẹ̀ sì ni Badagry kò sí nínú Nàìjíríà, ó kù díẹ̀, tí ẹ máa gbóorùn ara yín.
Kí Olúwa kí ó bùkún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; kí Olúwa Olódùmarè kí ó bùkún Ìránṣẹ́ Rẹ̀ sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, kí ààbò Ọlọ́run kí ó wà lórí wọn àti ọmọ wọn gbogbo.
Kí Olúwa kí ó ṣe Ìmọ́lẹ̀ fún Ìjọba-Adélé D.R.Y, kí ó ṣe Atọ́nà àti Ààbò fún olórí-Adelé, bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, kí ìgbà wọn kí ó yẹ ọmọ I.Y.P àti D.R.Y.