Ilé iṣé agbọ́hùn s’afẹ́fẹ́ kan ni ó fi ìròyìn kan síta láìpẹ́ yìí,nípa àìní inú dídùn àwọn ọmọ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fagídí jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, sí ríra ọkọ̀ òfurufú ayára bí àṣá tuntun olówó gọbọi tí ààrẹ wọn rà lásìkò tí ebi ń pa ará ìlú Nàìjíríà báyìí.
Yorùbá bọ̀, wọn ní, àìfini pe ni àìfi ènìyàn pe ènìyàn tí ń mú kí ará oko sán ‘bàǹtẹ́ wọ̀’lú ni ọrọ yí jẹ́ fún àwọn ará ìlú tí a ti kúròyìí.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tí a wà yí ni àwọn ará ìlú jáde síta láti fi ẹ̀hónú wọn hàn látàrí ebi,ìyàn àti ọ̀wọ́n gógó tó gba ìlú kan,síbẹ̀ etí ọ̀gbọìn ní ìjọba ayédèrú náà kọ́ sí igbe ara ìlú dípòo bẹ́ẹ̀, rírà ọkọ òfúrufú ayára bí àṣá ló mọ́ mú láyà àwọn afipá jẹ gàba yí , ọ̀rọ̀ yí wá dà bíi, baba ń jóná à ń béèrè irùngbọ̀n.
Gbogbo nkan wọ̀nyí ni màmá wa, ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla rí, tí wọ́n fi pinnu pé ìjọba ará ìlú ní yíó wà ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ní gbàrà tí àwọn Adelé wa bá tí wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ní gbogbo ìpínlẹ̀ méjèèje.
Ẹ jékí a dúpẹ́ lọwọ Olódùmarè tí O lo màmá wa ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti yọ ilẹ̀ Yorùbá kúrò l’óko ẹrú amúnisìn yíi, láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjì le lógún, tí a si ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa nípa ìbúra wọlé fún olórí Adelé wa, bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ojó Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún.
Láìpẹ́, láìjìnnà Olódùmarè yóò bá wa ṣí gbogbo àwọn tí wọ́n ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa nídìí, t’ọmọdé t’àgbà ni yóò sì rí ògo wa lò.