Olódùmarè tó ti ń rán wá lọ́wọ́ látẹ̀yínwá yóò túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ síi láti r’ẹ́yìn àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XLọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, ajẹgàba Nàìjíríà ntan ara wọn jẹ. Èyí tí ó pe’ra rẹ̀ ní Afeez Àlàbí, tí ó sọ pé òun ni Kọmíṣọ́nnà kan ní ibi tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà npè ní orúkọ tí kìí ṣe tiwa, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (Old Oyo Empire), tí ajẹgàba Nàìjíríà npè ní Kwara, tí ó nsọ̀rọ̀ nípa àlùmọ́nì ilẹ̀, sọ pé tọ́ọ̀nù lithium kan ní’ye lórí ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin dọ́là lọ,…a ò bi ẹ́ l’ẹjọ́ o, Afeez, kí aríremáse Nàìjíríà ó kúrò lórí ilẹ̀ wa la sọ.
Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ìròyìn náà sọ fún wa pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, wọ́n nwa lithium wa, bí ẹni pé àwọn ló nií, ní agbègbè Bani, ní apá ibi tí wọ́n npè ní Kaiama, ní Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (Old Oyo Empire), Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
A gbọ́ pé wọ́n ti ń ba ilẹ̀ àgbègbè náà jẹ́, torí olè kò bìkítà kí nkan bàjẹ́; èyí tó bá ṣáà ti rí kó yẹn l’ó wọ̀-ọ́ lójú; bẹ́ẹ̀ ni a gbọ́ pe omi agbègbè náà kò fi bẹ́ẹ̀ dára mọ́, torí àwọn èròjà olóró tí wọ́n nlò láti fi wa àlùmọ́ọ́nì náà nṣe aburú fún omi ibẹ̀.
Akótilétà Nàìjíríà nsun’kún pé àwọn tí kò ní ẹ̀tọ́ ló nwa àlùmọ́ọ́nì yí, ṣùgbọ́n àwa nsọ fún ajẹgàba Nàìjíríà, báyi, pe ilẹ̀ D.R.Y ni Bani, Nàìjíríà fún’ra rẹ̀, olè ni níbẹ̀. Jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa.
Agbègbè Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (Old Oyo Empire) kún fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun olówó-iyebíye tí ó jẹ́ àlùmọ̀nì ilẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe nfi ọgbọọgbọ́n pin yẹ́lẹyẹ̀lẹ láti àtẹ̀yìnwá, títí tí wọ́n fi gé apá kan mọ́ Kebbi àti Niger ní ajagun gbalẹ̀ Nàìjíríà, tí ó sì jẹ́ ilẹ̀ Yorùbá ni; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n pe apá kan ní ara Kogi wọn, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé ní báyì, ibi tí wọ́n fà mọ́ ara Kogi wọn, tí ó jẹ́ ilẹ̀ Yorùba, ni ó wà ní ara Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) bayi.
Odò Ọya ni Àlà Ilẹ̀ Yorùbá; gbogbo ìgbà tí wọ́n njí ilẹ̀ wa wọ̀nyí, kí ó tó di pé Ọlọ́run gbé Màmá wa dìde, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, láti fún wa ní ìgbàlà yí, àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní Ọba nwò, tí wọn ò rí nkankan ṣe si nítorí àjẹbánu wọn, àti wípé wọn ò kúkú ní agbára lábẹ́ òfin agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà wọn, nítorí òyìnbó amúnisìn ti rọ̀wọ́n lóyè tipẹ́.
Ṣùgbọ́n, ní ìsiìyí, D.R.Y ti dé! Nàìjíríà, kúrò lórí ilẹ̀ wa!