Ìbànújẹ́ kò sí fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) pàápàá jùlọ àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) nítorí pé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀.

Gbogbo àwọn àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè fi kẹ́ wa ní ilẹ̀ Yorùbá, fún ìgbá’yé gbádùn ọmọ Yorùbà ni, kìí ṣe fún ẹlòmíràn. Àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè D.R.Y yóò sì lò wọ́n láti ṣe ìtọ́jú wa dáadáa. 

Kò sí ìfòyà fún wa mọ́. Níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣáà ti jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti D.R.Y,  tí a sì ń pa òfin orílẹ̀ èdè wa mọ́, tí a ò gba àbọ̀dè fún ìran Yorùbá, gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ wa ni yóò tẹ̀ wá lọ́wọ́.

Àwòkọ́ọ̀ṣe rere ni orílẹ̀ èdè D.R.Y ní Áfríkà àti káàkiri àgbáyé. Gbogbo àgbáyé ni yóò máa wá wo àwọn ohun ìyanu tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè wa, nítorí pé, ìmọ́lẹ̀ ni a jẹ́, àwa sì ni ìmọ́lẹ̀ ògo adúláwọ̀.

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ìmọ̀ sọ̀kan kí a sì fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alámòójútó wa, kí iṣẹ́ náà leè rọ̀ wọ́n lọ́rùn, kí á sì leè bẹ̀rẹ̀ sí ńjẹ ìgbádùn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè fi rán Màmá wa MOA sí àwa ọmọ Yorùbà.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal