Ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni kí àwa ìran Yorùbá padà sílé, tó wá gbé ẹni bí ọkàn Rẹ̀ dìde láti jẹ́ iṣẹ́ náà. Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá, kí àánú àti ààbò Olódùmarè máa bá a yín gbé nígbà gbogbo.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa MOA sọ fún wa ní ẹgbàáọdún-ó-léméjìlélógún wípé, ohun tó ń bọ̀ kò ṣeé dúró wò rárá, a fi kí a tètè máa lọ sílé.
Ṣé àwa náà ti wá ríi báyìí wípé, kò sí irọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà. Èròǹgbà àwọn amúnisìn ni láti gba ilẹ̀ wa, kí wọ́n lè wá jókòó kí wọ́n máa pàṣẹ lórí ilẹ̀ àjogúnbá wa. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ wí pé, gbogbo àwọn ohun aṣekúpani ni wọ́n ń ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, (Democratic Republic of the Yoruba D.R.Y).
Olè ń wá bí kò ṣe láti pa, láti jí àti láti parun, àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè jogún fún wa ni ó wọ̀ wọ́n lójú tí wọ́n fi ń gbé irú ìgbéṣẹ̀ aṣekúpani báyìí.
Bí wọ́n ṣe ń kó abẹ́rẹ́ wá lóríṣiríṣi ni wọ́n ń kó irúgbìn GMO wá, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn oògùn olóró tí kò yẹ láwùjọ ọmọ ènìyàn. Wọ́n ń ṣe àwọn ọmọ Yorùbá lọ́ṣẹ́ ní ẹ̀ka ètò ìlera. Bí wọ́n ṣe ń ta kíndìnrín bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ta ẹ̀yà ara míràn. Oríṣiríṣi àìsàn ni wọ́n dà káàkiri, kí àwọn ènìyàn lè máa gba abẹ́rẹ́ aṣe’kúpani.
Àwa ọmọ Aládé aò leè rìn ká yan fanda lórí ilẹ̀ babańlá wa mọ́, nítorí ìbẹ̀rù àwọn agbénipa, wọ́n lé àwọn àgbẹ̀ lóko. Níbo ni à bá fi ojú sí tí kìí bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó gbé màmá wa MOA dìde.
Kò sí iṣẹ́, kò sí iná, ètò ààbò mẹ́hẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń halẹ̀ mọ́ àwọn ènìyàn wípé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn alágbàáyé náà fẹ́ sọ ara wọn di Olódùmarè, wọ́n fẹ́ kí gbogbo àgbáyé wà ní abẹ́ ìṣàkóso wọn. Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá ìran Yorùbá ti kó wa yọ, a ti bọ́ kúrò nínú ìgbèkùn, kí a máa jó, ká sì máa yọ̀ lókù nítorí pé, a ò tún padà sínú oko ẹrú mọ́ láéláé!