ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
(A lo fọ́nrán yí fún ẹ̀kọ́ nìkan, a sì ṣe ìdánimọ̀ fún àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ lórí rẹ̀)
A fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yí ó yé ẹnìkọ́ọ̀kan wa dáadáa, ìdí nìyí tí a óò fi ṣe àtúpalẹ̀ rẹ̀ ní èdè abínibí wa lẹ́sẹẹsẹ.
Gẹ́gẹ́ bí arábìnrin kan ṣe sọ lórí ẹ̀rọ ayélujára pé, ìjọba orílẹ̀ èdè Kenya lábẹ́ ìdarí William Ruto ti f’ọwọ́ sí lílo ìdánimọ̀ ìgbàlódé nípasẹ̀ ẹ̀rọ àìf’ojúrí fún àwọn ọmọ ìkókó àti fún gbogbo àwọn ọmọ ìlú orílẹ̀ èdè Kenya. Ìlànà yí sì ní àtìlẹ́yìn ilé iṣẹ́ Bill Gates.
Ètò náà fojú sí àwọn ọmọ tuntun tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, lẹ́yìn o bá ti bímọ tán kí o tó kúrò ní ilé ìwòsàn, wọ́n ò tún fún ọ ní ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rọ àìf’ojúrí tí wọ́n yóò fi sí ibì kan nínú àgọ́ ara ènìyàn, ẹ ro èyí dáadáa.
Arábìnrin náà ṣe àfihàn fọ́nrán Ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya níbi tí ó ti ń ṣe ìkéde lílo ẹ̀rọ àìf’ojúrí ọ̀hún nínú ètò kan tí ó sì ń wí báyìí wípé:
Ẹ̀rọ ìdánimọ̀ ti ìgbàlódé èyí tó ti jẹ́ ìpèníjà ńlá fún wa láti ọjọ́ pípẹ́ ti wà ní abẹ́ àyẹ̀wò báyìí fún bíi oṣù méjì síbi tí a wà yí.
Mo ti ní ìdánilójú nípasẹ̀ àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn àti àwọn Mínísítà pé ní oṣù Ọ̀pẹ aó leè ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀rọ ìdánimọ̀ tí gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Kenya kò ní nílò láti máa gbé ìwé, ike tàbí ohun mìíràn gẹ́gẹ́ bí ìdánimọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n nípa lílo yálà ojú wọn tàbí ìtẹ̀ka gẹ́gẹ́ bí ìdánimọ̀, wọ́n yóò sì tún leè ṣe kátà-kárà ní ìrọ̀rùn láì ṣe wàhálà nípa dídá wọn mọ̀ irú ẹni tí wọ́n jẹ́.
Àti pé, èyí tí ó wú ni lórí jùlọ nípa rẹ̀ ni wípé, aò nílò láti ná bílíọ̀nù owó bí àwọn èyí tí a ti ń ná lórí àwọn nǹkan mìíràn gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín náà ṣe mọ̀.
Èyí ni òpin ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya sọ.
Lẹ́yìn náà ni a rí fọ́nrán Bill Gates tó sọ báyìí wípé, a ó mú àwọn èròjà tí a ṣẹ̀dá sí àgọ́ ara àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ aó sì fi sínú iṣan wọn.
Arábìnrin tó gbé fọ́nrán náà sórí ẹ̀rọ ayélujára wípé, ọ̀rọ̀ náà tí wá fa oríṣiríṣi àríwísí láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Kenya.
Ẹni kan tilẹ̀ wípé, Bill Gates fẹ́ láti máa dárí gbogbo adúláwọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀rọ àìf’ojúrí, nítorí pé ó ṣòro fún lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí láti máa dárí ilẹ̀ Áfríkà àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Áfríkà, ó mọ̀ómọ̀ fi ẹ̀rọ àìf’ojúrí yí sára àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ kó leè máa dárí wọn ni.
Ẹlòmíràn náà tún kọọ́ wípé, tí ọ̀rọ̀ bá jẹ́ òótọ́, a jẹ́ wí pé, Ààrẹ Orílẹ̀ èdè Áfríkà míràn tún fẹ́ dìde láti jẹ́ kí wọ́n dán nkan wò lára àwọn ènìyàn, nítorí owó.
Ní àkótán,gbogbo àwa ọmọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra gidi. Bill Gates kò dákẹ́ bẹ́ẹ̀ni kò simi lórí èròǹgbà rẹ̀ láti dín iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní àgbáyé kù pàápàá àwa aláwọ̀ dúdú, ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wípé àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní aṣojú tó yẹ kí wọ́n dáàbò bo àwọn ará ìlú, àwọn gan-an ni wọ́n ńṣe agbódegbà àwọn ẹni ibi wọ̀nyí nítorí àtẹnujẹ.
Ẹ jẹ́ kí a mọ̀ wípé àwọn amúnisìn wọ̀nyí kò fi ibi kankan dára jù àwa aláwọ̀ dúdú lọ. Èròǹgbà wọn ní láti pa àwọn aláwọ̀ dúdú kí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.
Orí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ló tún kàn báyìí, láti leè máa dárí wọn bó ṣe wù wọ́n, ọmọ tí wọ́n bá sọ fún pé kò dìde níbi tó wà yẹn, kò lọ wu ìwà báyìí, lọ́gan ni ọmọ náà yóò lọ síbi tí wọ́n bá dárí rẹ̀ sí. Ohun tí wọ́n fẹ ṣe nìyí, kí gbogbo aláwọ̀ dúdú wà ní ìkáwọ́ wọn.
Ìmúnisìn ti ìgbàlódé ni eléyìí, ohun tí àwọn amúnisìn yí kò le gbà ni wọ́n fi ń lọ̀ wá ní Afrika. Tí àwọn ọ̀dàlẹ̀ asíwájú náà bá sì ti rí owó, wọn ò kọ̀ láti ta ìran wọn.
Fún ìdí èyí, àwa ọmọ Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àánú rẹ̀ lórí ìran Yorùbá, tó rán màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn amúnisìn wọ̀nyí, nítorí pé ìjọba D.R.Y kò ní gba àbọ̀dè fún ìran wọn láíláí.
Ní àkótán, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), nílé lájò, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra fún abẹ́rẹ́ àjẹsára, oògùn òyìnbó, tàbí gbogbo ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ètò ìlera lápapọ̀. Ìgbà díẹ̀ ló kù, ẹ má jẹ́ kí àwọn apaná ògo yí ó rí wa mú, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìtọ́jú ara wa ní ìlànà ti àwọn babańlá wa, Olódùmarè ti gbé wa borí.