Àǹfààní tí ó pọ̀ ló wà lára àwọn oúnjẹ wa ti à ń jẹ ní ilẹ̀ Yorùbá, gbogbo àwọn oúnjẹ wa ni wọ́n máa ń ṣe ara lóore tí a bá pèsè wọn fún jíjẹ ní ọ̀nà tí ó tọ́.
Gbogbo wa ni a mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí a ń lo àgbàdo fún ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n èyí tí mo fẹ́ pe àkíyèsí wa sí ní apá ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa kii kà sí.
Tí àgbàdo tútù bá ti jáde, gbogbo wa ni a máa ń ṣèé jẹ́ pẹ̀lú omi, tàbí kí á taá ní orí iná, a ó jẹ ẹ́ tán tí a ó sì sọ sùkù rẹ̀ nù.
A tún máa ń rẹẹ́ nínú omi gbígbóná dí ọjọ́ kẹta kí ó baà lè rọ̀ lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti yín in kúrò lára sùkù tán láti lè fi ṣe ògì. Gbogbo wa ní a ní ẹ̀rọ nínú ilé ìdáná wa, tí a bá ti wa àgbàdo yìí kúrò nínú omi tí a fi rẹ ẹ́, a máa wá tún un fọ dáadáa pẹ̀lú omi tí ó mọ́, kí á wá bẹ̀rẹ̀ sí máa lọ ọ́ díẹ̀ díẹ̀ tí ó máa fi kùnà bí ìgbà tí a bá lọ ata ọbẹ̀.
Tí a bá ti lọ gbogbo àgbàdo náà tán, kí á wá bù omi sí orí ògì náà, kí á dé e mọ́lẹ̀ di ọjọ́ kejì, ògì wa ti dé nìyẹn o, tí ó máa rọra kan díẹ̀ lẹ́nu, èyí tí ó fi ṣe adùn nìyẹn.
Ohun tí mo fẹ́ fà yọ níbẹ̀ ni pé, tí a bá ti lọ ògì wa kùnà bí ata ọbẹ̀, kò sí ìdí fún wa láti máa fi àṣẹ jọ èérí kankan kúrò nínú ògì náà, nítorí pé, àgbàdo tí a ṣe ní omi gbígbóná jẹ tabi ti a ta á jẹ, a kò yọ èérí kankan kúrò ní ibẹ̀, nítorí èyí ni wọ́n ń pè ní odindi àgbàdo tí ó ní èròjà tí ó máa ń ṣe ara loore ninu.
Àbí ẹ kò kíyèsí àwọn ewúrẹ wa tí a máa ń fún ní èérí yìí jẹ ní bí ara wọn ṣe máa ń dán yọ yọ yọ?, àbí, ṣé ẹnikẹ́ni ń lo ìpara fún wọn ni bí?, tí wọ́n bá jẹ èérí tán, wọ́n máa tún bọ́ sí’nú igbó, wọn máa jẹ èwe tútù síi, irun ara àwọn ewúrẹ máa ń dán bí ẹnì pé ènìyàn fi àdí tàbí orí pa irun ara wọn ni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á kíyèsí i ìmọ̀ràn yìí.





