Orílẹ̀-èdè Singapore tí ó jẹ́ wípé àwọn ni ó gba abẹ́rẹ́ àjẹsára covid 19 jùlọ ní àgbáyé ti ń fojú wi’ná báyìí o, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe gbọ́ọ nínú ìròyìn kan wípé, iye àwọn tí ó ń kú ń pọ̀jù àwọn ọmọ tí wọ́n ń bí lọ, bí ó ti jẹ́ wípé abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ti mú kí ó nira fún àwọn ènìyàn láti ní oyún tí àwọn ènìyàn sì ń kú bí adìyẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tilẹ̀ ní ṣe àìsàn rárá ṣùgbọ́n tí wọ́n á kàn dédé kú lójijì.
Ní ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, ipò kínní ni orílẹ̀ èdè Singapore wà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè tí ó ní àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn tí ó ń kú jùlọ ní àgbáyé, nígbà tí ó wà di wípé ọ̀rọ̀ náà ti fẹ́ máa fa oríṣiríṣi ìbéèrè tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà sì ti fẹ́ máa gbójú agan sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ń ṣe ni wọ́n tètè yọ orúkọ orílẹ̀ èdè Singapore kúrò nínú ìwé àkọsílẹ̀ náà, pabanbarì rẹ̀ wá ni wípé, àwọn ìjọba orílẹ̀ èdè náà yọ òfin tí ó wà fún ṣíṣe ìwádìí tí ènìyàn bá kú látàrí gbígba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn kúrò nínú ìwé òfin wọn nígbà tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Singapore ti ń béèrè wípé ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára covid 19 ni ó ń fàá tí àwọn ènìyàn wọn fi ń kú ni.
Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè Singapore sì ń tan àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ wípé, orílẹ̀ èdè wọn ní o ní àkọsílẹ̀ tí ó kéré jù lọ nípa iye àwọn ènìyàn tí ó ń kú ní àgbáyé, ṣùgbọ́n ìdàkeji ọ̀rọ̀ mínísítà yí ni ó wà nínú ìwé àkọsílẹ̀ ti àgbáyé.
Gbogbo ìwà ìtannijẹ àti ìṣe’kúpani bí eléyìí kò ní sí ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, nítorí pé gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa, pé ní orílẹ̀ èdè ti wa, a ò ní gbójúlé oògùn àwọn aláwọ̀ funfun láì ṣe ìwádìí rẹ̀ fínífíní, pàápàá jùlọ a máa fí àyè gba lílo ewé àti egbò wa fún ìtọjú ara wa ti ìwádìí lórí rẹ̀ yíò sì máa lọ déédé lóòrè kóòrè fún ìtẹ̀síwájú àti ìsọdọ̀tun rẹ̀.
A tún gbọ láti ẹnu màmá wa tí Olódùmarè rán fún ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorúbá, ìyáa wa Olóyè Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla pe, èyíkéyìí nínú àwọn olóṣèlú wa tí ó bá da ọwọ́ rú, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni a ó da ẹsẹ̀ òun náà rú pẹlú ìjìyà tí ó tọ́, nítorí náà kò ní sí àyè láti parọ́ fún àwa I.Y.P. lórí ohun kankan, gbogbo òtítọ́ ní àwọn olórí ìjọba wa yóò máa sọ fún wa nígba gbogbo.
Gbogbo àwọn adarí wa ní wọ́n yóò nífẹ̀ẹ́ ìran Yorùbá tọkàntọkàn, tí wọ́n yóó sì ṣetán láti sin ilẹ̀ babańlá wọn pẹ̀lú ìfẹ́ àti òtítọ́ nítorí pé lẹ́yìn Ọlọ́run, ìran Yorùbá ni.