BÍ ÀWỌN ÒYÌNBÓ ALÁWỌ̀ FUNFUN ṢE Ń KÓ ỌRỌ̀ ÀWA ADÚLÁWỌ̀
Bí àwọn òpònú olóṣèlú ní ilẹ̀ adúláwọ̀, pàápàá ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ṣe ń ronú oríṣiríṣi ọ̀nà láti jí owó kó sí àpò ara wọn, bẹ́ẹ̀ náà ní àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ń ronú nígbà gbogbo oríṣiríṣi ọ̀nà tí àwọn ó tún gbà láti leè túbọ̀ máa kó àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì wa, síwájú àti síwájú […]