ỌGBỌ́N LÁTI FI OWÓ-ORÍ ṢE IBI FÚN ÁFRÍKÀ
Inúnibíni kò kan tí àìmọ̀ ìwà hù. Èyí ló d’ífá fún bí àwọn ẹni-ibi òyìnbó-amúnisìn ṣe ńfi ojojúmọ́ wá ọ̀nà láti fí Áfríkà sí abẹ́ ìsìnrú wọn láì sí ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí Áfríkà ṣẹ̀ wọ́n. Òyìnbó ṣáà ń bínú wa. Àbí kí ló kan òyìnbó pẹ̀lù owó-orí àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ní ilẹ̀ adúláwọ̀? Tani kò […]