Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ fún wa lọ́jọ́ àjọ̀dún ọdún-kéjì tí a ti jáde kúrò nínú Nàìjíríà, èyí tí a ṣe ìkéde-Òmìnira náà ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, tí àjọ̀dún kéjì náà sì wáyé ní ọjọ́’Rú, ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún; wọ́n jẹ́ kó yé wa pé kí a máa wo amóhùnmáwòrán iypdryTV, lóòrè-kóòrè! Màmá sọ pé kìí ṣe ẹnikẹ́ni tàbí èyànkan ló ni iypdryTV! ỌMỌ YORÙBÀ ló ni iypdryTV, ORÍLẸ̀-ÈDÈ D.R.Y ló ni iypdryTV .
Ká jẹ́ kí ó ye wa dáadáa: Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá sọ pé D.R.Y ló dá amóhùnmáwòrán iypdryTV sílẹ̀, D.R.Y ló nií, kìí ṣe amóhùnmáwòrán ẹnikẹ́ni, kò sì sí ní ìfiga-gbá-‘ga pẹ̀lú ẹnìkànkan.
Màmá wa MOA sọ pé kò sí ohun kankan tí amóhùnmáwòrán iypdryTV máa ńgbé síta ju ohun tí ó jẹ́ ti I.Y.P àti D.R.Y nìkan – kìí ṣe aládani, ti ọmọ Yorùbà ni, orílẹ́-èdè D.R.Y ló ni.
Màmá sọ pé kí a máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó kó ìdani-lọ́pọlọ-rú bá wa ní orí ọ̀rọ̀ yí! Wọ́n ní a ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó tún ṣubú mọ́! àfi tí ó bá jẹ́ pé a rí ẹni tí ó ti yan ìṣubú.
Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè Yorùbá ni àkọ́kọ́.