A kì í ní k’ọ́mọ ẹni má d’ẹ́tẹ̀, tó bá ti lè dá’gbó gbé
Àwọn ẹ̀ka tó ńṣiṣẹ́ fún ìjọba tó ńfi agídí jẹgàba lórí ilẹ̀ wa nílu Èkó, fún ètò àyíká ṣiṣẹ́ ní alẹ́ ọjọ́ ìsinmi láti ṣe àtúnṣe àyíká àwọn àdúgbò kan ní agbègbè Erékùṣù Victoria, Alága wọn ní ẹ̀ka náà, ọ̀gá ọlọ́pǎ Adétáyọ̀ Akerele sọ pé iṣẹ́ náà wáyé nítorí ìkérora láti agbègbè náà.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XAlága náà tún ṣọ pé, ó lè ní wákàtí mẹ́ta tí àwọn fi ṣiṣẹ́ ní àdúgbò Akin Adesola àti Adetokunbo Ademọ́la tí wọn sì fi ọwọ́ òfin Nàìjíríà mú àwọn kan tí wọn sì gba ọja wọn.
Ó’ wá ṣe ìkìlọ̀ pé iṣẹẹ́ yí yíò máa tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Èkó fún ìmọ́tóto.
Àwa ọmọ Yorùbá níláti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a ò bẹ ẹnikẹ́ni níṣẹ́ rara, ó yẹ kí wọ́n gbé ìmọ́tóto wọn lọ sí Abùjá ní Nàìjíríà.
Láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí ìjọba orílẹ̀-èdè wa Democratic Republic of the Yorùbá tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ló yẹ kí àwọn àkànṣe iṣẹ tí bẹ̀rẹ̀ nípa àwọn ètò tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ti là kalẹ́ tí à sí ti mọ́, àwọn iṣẹ́ bíi gbígbẹ́ kòtò ìdamminù geere, ètò látí gbé àwọn agbada ìkólẹ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà wa káàkiri àti ìpèsè àwọn ọkọ̀ akólẹ̀ kò ìdọ̀tí fún ìmọ́tóto àyíká àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n àwọn agbésùnmọ̀mí Naijiria tó ń jẹgàba lórí ilẹ wa ní wọ́n ńfa ìdíwọ́, wọn sì ńṣẹ̀ sí òfin àgbáyé nípa lílo ọwọ́ agbára láti dí orílẹ-èdè wa lọwọ ìtẹ̀síwájú.
Gbogbo àwa IYP gbọ́dọ̀ dide ní kíákíá láti jẹ́ kí ìjọba Nàìjíríà agbésùnmọ̀mí mọ wípé ilẹ̀ Yorùbá ọmọ Yorùbá ló ní.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
Ìgbé-Ayé Tinubú – Ìgbé-Ayé Irọ́ Pátá Gbáà Ni
Oríṣiríṣi Ọ̀rọ̀ Tí Kò Ní Ìtumọ̀ Láti Ẹnu Àjọ Ecowas!
Ó Màṣe Ò! Ọ̀dọ́’mọkùnrin Kan Ṣe’kúpa Bàbá Rẹ̀ Láti Fi Ṣe Ètùtù Ọlà!