Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìròhìn kan tí a rí gbà, tí ó dẹ̀ ti wà nílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, sọ o, pé nígbàtí ẹni kan tí àwọn kan pè ní ìyá tí ó bí Tinubú, ààrẹ Nàìjíríà, tí ó kú, Tinubú kò fara hàn ní’bi ìṣòkú náà rárá!
Èyí túmọ̀ sí wípé, Tinubú kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó pe òun ní ọmọ obìnrin ọ̀ún. Ṣé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtan àti oríṣiríṣi àwọn ọ̀rọ̀ míràn ni ó kúkú ntẹ̀lé ọ̀rọ̀ Tinubú yí káàkiri! Àbí àkúdàáyà ti ẹ̀ ni okunrin ọ̀ún ni?
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XṢùgbọ́n ṣá, ohun tí akọ̀tàn kan, Kòfẹ́sọ̀ Ṣiyan Oyèwẹ̀sọ̀, tí ó sọ ní ọdún 2006, ní ìlé-ẹ̀kọ́ fásitì ìpínlẹ̀ Èkó (LASU), fihàn wípé Bọ́lá Ahmed Tinubú kàn njẹ́ orukọ Tinubú ni, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò bá ìran Tinubú tan ní ọ̀nàk’ọnà!
Ta wá ni bàbá Tinubú gan? Ìran wo ni Tinubú? Ohun tí ó dá’ni lójú ni wípé, Bọ́lá Ahmed Tinubú ní nkankan tí ó gbé pa mọ́, tí kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó mọ̀ nípa òun. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó mọ orísun òun!
KÍ NI TINUBÚ NGBÉ PAMỌ́? Èrèdí kí ni ó ṣe ngbée pamọ́?