A kì í ní k’ọ́mọ ẹni má d’ẹ́tẹ̀, tó bá ti lè dá’gbó gbé
ECOWAS tún ti gbé tuntun dé o! Àwọn wo ni ECOWAS? Àwọn apapọ̀ orílẹ̀-èdè ní ìwọ̀-oòrùn Áfríkà, tí wọ́n pa ara wọn pọ̀ láti dòwò papọ̀ látàrí kí ọ̀rọ̀ ajé ó lè dẹrùn káàkiri agbègbè náà.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XṢùgbọ́n ṣá o, láti iye ọdún tí wọ́n ti kó’ra papọ̀ yí, a ò mọ̀ bóyá wọ́n rí ànfààní kankan gbé jáde o!
Nítorí, ká fi lé tiwa, a ò rí ohun tí ó jẹ́ ìrọ̀rùn fún àwọn orílẹ̀-èdè, tí a bá wo ìgbé-ayé ará ìlú wọn; ní àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ àjọ náà.
Láìpẹ́ sẹ́hìn náà ni àwọn orílẹ̀-èdè Burkina Faso, Mali, àti Niger sọ wípé ECOWAS yí kò pé wọn, tí wọ́n sì yọ ara wọn kúrò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn tókù ti ní ẹ̀fọ́rí tó lágbara láti ìgbà tí àwọn mẹ́ta yẹn ti yọ ara wọn, tí wọ́n sì nwá ọ̀nà oríṣiríṣi láti fà wọ́n padà.
Nàìjíríà ni ilú tí ó tóbi jù láarín ECOWAS náà, a ò dẹ̀ mọ ìrọ̀rùn tí ó dé bá ọmọ ìlú Nàìjíríà nípasẹ̀ ECOWAS. Ṣé ìyẹn kò tiẹ̀ kàn wá nígbàtí a ò kìí ṣe Nàìjíríà, ṣùgbọ́n a ní láti máa wo kíl’onṣẹlẹ̀ ní àyíká wa, kí a má rí pàjáwìrì burúkú.
Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ so wípé ECOWAS npète láti ní ìdiwọ̀n owó kannáà, èyí tí wọ́n máa pè ní ECO, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 2027.
Gẹ́gẹ́bí ìròhìn tí a gbọ́, wọ́n sọ wípé lílo ìdiwọ̀n owó kan náà yíò jẹ́ kí ìrìnnà ọjà àti ti ènìyàn káàkiri àwọn ìlú tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ wọn ó túbọ̀ já geere si. Ọgbọ́n ni ènìyàn gbọ́dọ̀ fi wo ọ̀rọ̀ náà. Èkíní, kò sí òfin tí ó sọ wípé, dan-dan-dan, ìlúkílu kan gbọ́dọ̀ fi tipátipá wà nínu àjọk’ajọ kan!
Èkejì, àwa Yorùbá ti sọ wípé a máa mọ odi káàkiri àyíká ilẹ̀ àjogúnbá wa; a ò le gbà kí ilẹ̀ Yorùbá ó tún wá di ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni, láti ibikíbi, yíò máa wọ’lé wọ’de bí ó ti wù wọ́n. Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmare, Yorùbá Ni.
Oríṣiríṣi àwọn ìgbésẹ̀ tí oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè tàbí àjọ, ngbé, yàtọ̀ sí ìṣẹ̀dá àti ìlàkalẹ̀ Olódùmarè fún ìran Yorùbá ni aò ní gbà láàyè fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Bẹ́ẹ̀ náà ni a gbọ́ nínú ìròhìn náà, nípa káàdì ìdánimọ̀ tuntun tí ìlú tó fẹ̀gbẹ́ tì wá, Nàìjíríà, npète rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti oṣù kẹ́jọ ọdún yí. Kí ọmọ Yorùbá kankan máṣe lọ gbàá o! Má sọ ìj’ọmọ-Yorùbá ẹ, má sọọ́ nù o!