Fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí ọ̀dọ́’mọdékùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ridwan Adewale tí ó sì ń kà bòòròbò, arákùnrin yí ṣe ikú pá bàbá rẹ̀, ó ní òhún fi ṣe ètùtù ọlà nítorí àìríjẹ.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ọ̀dọ́’mọdékùnrin náà ṣeé láàyè wípé, nígbà tí ìyà náà pọ̀ lápọ̀jù ni òhun ṣe fi oókan kún eéjì, tí òhun sì gba ilé aláwo lọ láti ṣe ètùtù ọlà yí.

Babaláwo náà sì béèrè fún nǹkan ọmọkùnrin bàbá rẹ̀ láti fi ṣe ètùtù, èyí tí ọ̀dọ́’mọdékùnrin náà sì faramọ́ọ.

Ibi tí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ní ó sì ti ń jẹ́wọ́ wípé, okùn àti ọ̀bẹ ni òhun lò láti fi pa bàbá náà tí òhun sì gé nǹkan ọmọkùnrin bàbá rẹ̀ fún ètùtù.

Ọ̀dọ́’mọdékùnrin yí ṣeé láàyè síwájú síi nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, óní láti ìgbà tí òhún ti ṣe ètùtù ọlà na, owó kéékèèké ni òhun ń rí, bí àpẹẹrẹ, nígbà míràn, ó lè má ju ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀ náírà (50,000 Naira) tàbí ọ̀kẹ́ márùn-ún náírà (100,000 Naira) tí kò sì ju owó oúnjẹ lọ.

Óní òhun pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti àbúrò òhun ni àwọ́n jọ má ún na owó na.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024

Ọ̀dọ́’mọdékùnrin yìí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe ri nínú fọ́nrán náà ni ó wá ń gba àwọn ọ̀dọ́ akẹgbẹ́ẹrẹ̀ níyànjú láti má fi ìkánjú lá’bẹ̀ gbígbóná, ṣùgbọ́n kí wọ́n dúró de àsìkò Ọlọ́run.

Àwa ọmọ Olómìnira Yorùbá tiwantiwa fi àsìkó dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla fún gbígbà tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìyà, òsì, àìríjẹ àti àìrímú, bí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣé bí à bá ṣe máa balọ rèé tí ọmọ ń fi bàbá tó bíi ṣe ètùtù ọlà, ohun ìbaninínújẹ́ pátápátá gbáà ni eléyìí.