Ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́rùn-ún ìgò ọtí líle ayédèrú tí ọkọ̀ àjàgbé kan ń gbé láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ sí ilẹ̀ adúláwọ̀ o, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé Olódùmarè tú wọn ní àṣírí tí wọ́n sì ti gba ọkọ̀ àjàgbé náà sílẹ̀ báyìí fún ìwádìí.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe gbọ́ nínú ìròyìn náà wípé, oríṣiríṣi èròjà aṣe’kúpani ni wọ́n fi ṣe ọtí náà tí ó sì jẹ́ pé ní ilẹ̀ adúláwọ̀ ni wọ́n ń ko lọ, ọtí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johnnie Walker black label whisky ti ní ayédèrú báyìí o.
Gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ojúlalákàn fi ńsọ́’rí, pàápàá ní àkókò tí a wà yí, nítorí gbogbo ọ̀nà ni àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun yìí ń gbà láti ríi dájú pé wọ́n pa àwa ìran Akẹbólà run lórí ilẹ̀, ṣùgbọ́n Olódùmarè kò ní gbà fún wọn.
Àwọn kan yìí náà ni wọ́n ń ṣẹ̀dá oríṣiríṣi àìsàn, àwọn yìí náà ní wọ́n ń gbé abẹ́rẹ́ ikú kiri, ẹ tún wo ọ̀nà míràn tí wọ́n tún ń gbà báyìí.
Kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí Ó rán ìránṣẹ́ Rẹ̀, màmá wa, Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla sí wa ní àkókò yìí, láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ ikú wọ̀nyí, nítorí wípé ní kété tí àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí tí wọ́n ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa wọ̀nyí bá ti kúrò, tí àwọn Adelé wa bá sì ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ lìjọba ní ìpínlẹ̀ wa kọ̀ọ̀kan, láti tèsíwájú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ààbò tó nípọn yóò wà ní gbogbo àwọn ẹnu ibodè wa, tí a ó sì máa ṣe ọ̀fíntótó ohunkóhun tí ó bá ń wọlé tàbí jáde ní orílẹ̀ èdè wa.
Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a f’ọwọ́sowọ́pọ̀, kí a sì ti àwọn Adelé wa lẹ́yìn nígbàkùgbà tí a bá gbọ́ ìpè láti ẹnu àwọn adarí wa wípé, àkókò ti tó láti lọ ṣe àjọyọ̀, ẹ jẹ́ kí a túyáyá-túyàyà jáde láti lọ fi ẹ̀mí ìm’oore wa hàn sí Olódùmarè.