Èyí ni l’ati sọ fún Ìjọba agbésùnmọ̀mí Nigeria, àti àwọn ẹmẹ̀wà wọn tó jẹgàba lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, D.R.Y; lára èyí tí a rí Adémọ́lá Adélékè tí ó pera rẹ̀ ní gómìnà, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó pera rẹ̀ ní Ọ̀gá Ọlọ́pa ní bẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ọlọ́pa agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ni, kìí nṣe ọlọ́pa D.R.Y, pàápàá ẹni tí ó njẹ́ Gíwá Àlàdé Emmanuel, tí ó pe’ra rẹ̀ ní Igbákejì-Abẹnugan “Ọlọ́pa Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun” àti ilé-Iṣẹ́ ìròyìn tí wọ́n npè ní “Daily Post,” àti ilé iṣẹ́ Radio tí ó gbé ìròyìn Daily Post ọ̀ún jáde, èyí tí ó sọ̀rọ̀ nípa pé wọ́n mú àwọn kan ní ọjà Ọbádá ní ìlú Ìkirè, tí wọ́n sì pè wọ́n ní “Àjìjàngbara Odua Nation” tàbí “Yorùbá Nation;” èyí ni láti sọ fún gbogbo ẹ̀yin tí a dárúkọ wọ̀nyí, àti àwọn míràn bí tiyín, pé, Ọ̀DARÀN pátápátá ni ẹ jẹ́, tí ẹ̀sùn yín sì jẹ́ ẹ̀sùn “ìkọlu-orílẹ̀-edè aṣèjọba-ara-ẹni, èyí tí gbogbo ayé mọ̀ sí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y)“, èyí tí ó ti jáde kúrò lára aríremáse Nàìjíríà yín láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, tí ó sì ti di orílẹ̀-èdè Aṣèjọba-Ara-Ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, nígbà ti a ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí Ìjọba Adelé D.R.Y, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, tí orúkọ wọn sì ti wà níwájú àjọ Àgbáyé gẹ́gẹ́bí Olórí-Ìjọba D.R.Y.
Orílẹ̀-Èdè D.R.Y yí ni gbogbo ẹ̀yin tí a dárúkọ rẹ̀ yí ṣe àkọlù sí o, ṣùgbọ́n tí ẹ ntan ara yín jẹ pé “ajìjàngbara” ni orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni D.R.Y, tí ẹ̀yin agbésùnmọ̀mí nàìjíríà njẹgàba lórí ilẹ̀ wa!
Ẹ̀yin wá npa irọ́ pe ajìjàngbara ni “Yorùbá Nation” àti pé ìlú yín apaná ògo Nàìjíríà ti fi òfin de “ajìjàngbara Yorùbá Nation” – àh! L’ẹnu yín?
Ìwọ Adémọ́lá Adélékè, tìẹ ti bá ẹ! Wàá ro ẹ̀jọ́ níwájú àgbáyé! Ìwọ Gíwá Àlàdé Emmanuel, wàá fi ẹnu ẹ yẹn gbo’lẹ̀ ní àìpẹ́ yí: kò pẹ́ mọ́!
Ẹ̀yin oní’wé-ìròyìn Daily Post, tí ẹ gbé ìròyìn tí kò dúró lórí òótọ́ já’de, ẹ máa tó gbọ́ òórùn ara yín láìpẹ́; ẹ̀yin akàròyìn ilé-iṣẹ́ radio tí ó gbé àdàmọ̀dì ìròyìn Daily Post yí já’de, tí ẹ tún nsọ Yorùbá l’ẹnu, tí ẹ nṣ’ẹ̀fẹ̀, kí ẹ mọ̀ báyi, pé tiyín ti tán ní Ilẹ̀ Yorùbá, ní kété tí ìjọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá ti wọ’lé sí àwọn oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ wa, èyí tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun jẹ́ òkan lára rẹ̀!
Ẹ̀yin wá nfi orílẹ̀-èdè Yorùbá ta’yín? ẹ npè wá ní “ajìjangbara”? Ah, á tó yé yín!
Èyí tí ẹ nṣe yí, ó yé wa-à: ẹ mọ̀ pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá dáduró, ó sì ti yàtọ̀ sí Nàìjíríà pátápátá, ṣùgbọ́n ẹ fẹ́ lo ọgbọ́n àrékérekè, láti yí ọ̀rọ̀ náà sí òdì: kí àwọn ará-ìlú máṣe mọ̀ pé Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè Aṣèjọba-Ara-Ẹni, ṣùgbọ̀n kí wọ́n le máa ro pé ajìjàngbara ni wá, rárá o, ara yín ni ẹ ntàn jẹ!
Ẹ wá fẹ́ máa da ọpọlọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Yorùbá rú, àbí? ẹ ti ṣìí ! Ẹ npè Yoruba Nation ní “ẹgbẹ́ ajìjàngbara” – ah, kò níí dáa fún yín!
Ẹ máa jẹ ìyà ohun tí ẹ ṣe yí! Ẹ nda àwọn ènìyàn, ọmọ Yorùbá, lórí rú (Confusion), kí wọ́n máṣe mọ̀ pé Orílẹ̀-Èdè aṣèjọba-ara-ẹni ni Yorùbá lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, àti títí ayé, ṣùgbọ́n kí wọ́n máa rò pé wọ́n ṣì nṣe “ìjàngbara” lọ́wọ́ ni! Bí ẹ ṣe fẹ́ da orí ọmọ-Yorùbá rú yí (Confusion), ayé yín bẹ̀rẹ̀ sí dàrú láti òní lọ!
Ẹ wá nmú ìrònú àwọn ọmọ Yorùbá yà bàrá (Distraction) kúrò ní ọ̀nà tí Olódùmarè nmú wa tọ̀!
A ti ṣe ìkédé òmìnira wa, a sì ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni, ìjọba wa sì ti nṣiṣẹ́ lọ gẹ́gẹ́bí ìjọba orílẹ̀-èdè: ẹ lọ béèrè káàkiri àgbáyé Yorùbá ti dá dúró: kí ẹ yé mú ìrònù ọmọ Yorùbá yà bàrá (Distraction) kúrò ní ọ̀nà tí a nlọ: ohun tí a fẹ́ ṣe báyi ni kí àwọn ìjọba adelé wa ó máa tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, nípa wíwọ ìnú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, ní ilẹ̀ Yorùbá, tí a sì máa ṣe àjọyọ̀ alárinrin káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ D.R.Y, èyí tí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti ìlú Òṣogbo jẹ́ ọ̀kan.
Ẹ̀yin wèrè wọ̀nyí, tí ẹ fẹ́ máa fa yíyà-bàrá (Distraction) àti dídani-l’orí-rú (Confusion), ẹ ti ṣìí!
Àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ má ṣe jẹ́ kí ìsọkúsọ ọ̀rọ̀ tí àwọn tó pera wọn ní Ọlọ́pa, tí ó jẹ́ pé agbésùnmọ̀mí ajẹgàba ni wọ́n; ẹ má ṣe jẹ́ kí ìsọkúsọ wọn ó dà wá lóri rú: a kì nṣe ajìjàngbara, orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni ni wá; wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, wọ́n máa kúrò lórí ilẹ̀ wa láìpẹ́!
Àwọn tí wọ́n sọ pé wọ́n lọ ṣe ìwọ́de ìsọ̀rọ̀sí’ta (awareness) ní Ọjà Ọbádá, ní Ìlú Ìkirè, tí àwọn tí ó pera wọn ní ọlọ́pa, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ agbésùnmọ̀mí ìránṣẹ́ ajẹgàba nàìjíríà sọ pé àwọn mú yí, wọ́n ṣe lòdì sí ọ̀rọ́ Olórí Ìjọba-Adelé wa: bábá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́: lẹ́yìn tí Bàbá wa ti sọ fún gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) pé kí ẹnikẹ́ni máṣe lọ ṣe ohunkóhun mọ́ ní ìgbòro, kí á wà ní ìmúra-sí’lẹ̀ fún àkókò tí a máa ṣe Àjọyọ̀ ní pápá-ìṣeré tí ó tóbi jùlọ ní gbogbo ìpínlẹ̀ wa méjèèje; tí Màmá wa náà sì ti sọ́ pé ohun kan tó kù ni àjọyọ̀ tí a máa ṣe, lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àṣẹ wọ̀nyí, àwọn kan tún láyà, wọ́n ṣe lòdì sí ọ̀rọ̀ ìjọba-Adelé wa; wọ́n lòdì sí àṣẹ ìjọba Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, wọ́n ní àwọn lọ ṣe ìpolongo (awareness) ní ìlú Ìkire; wọ́n ti tápá sí òfin àti àṣẹ olórí-ìjọba D.R.Y. Olóṣèlú ni wọn nṣiṣẹ́ fún, wọn ò ṣiṣẹ́ fún D.R.Y; ẹni tó nṣiṣẹ́ fún D.R.Y kò ní dá ìfẹ́ inú ti ara rẹ̀ ṣe, ní ìlòdì sí òfin àti àṣẹ tí ó ti jáde l’ẹnu Olórí-Adelé wa, pé kí ẹnikẹ́ni ó máṣe já’de mọ́! Àwọn yí dá ìfẹ́ inú ara wọn ṣe! Wọ́n tàpá sí òfin Olórí Ìjọba Adelé D.R.Y.
A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ọkùnrin kan tí ó njẹ́ orúkọ àpèmí “Jesus is the Rock,” pé olóṣèlú ni, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ìkan nínú àwọn tí wọ́n rán sí àárin wa, tí àwọn adári wa sì ti yọ kúrò láarín wa tipẹ́, nígbàtí wọ́n ri pé olóṣèlú ni, kò sí fún òmìnira.
Ọkùnrin “Jesus is the Rock” yí, ni ó pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n npè ní “Ondo TV,” Jesus-is-the-Rock ló rán Ondo-TV (tí orùkọ rẹ̀ njẹ́ Fágbuyì) lọ sí Ìkirè, wọ́n jọ pàdí àpò pọ̀ ni, iṣẹ́ olóṣèlú ni wọ́n nṣe, tí àwọn tó pera wọn ní ọlọ́pa wá mú Fágbuyì àti àwọn míràn ní Ìkirè.
Gbogbo wọn jọ ṣiṣẹ́ papọ̀ ni: èyí tí ó pe’ra rẹ̀ ní gómìnà (Adémọ́lá Adélékè) mọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ni wọ́n rán wọn síta, àwọn náà ni wọ́n ní kí ọlọ́pa mú wọn, kí wọ́n pè wọ́n ní “ajìjàngbara” (agitator), kí àwọn ará-ìlú lè rò pé a ò tíì di orílẹ̀-èdè, pé “ajìjàngbara” ni wá, tí èyí sì jẹ́ irọ́ gbáà! Wọ́n jọ dìí ni!
Ẹ̀yin olóṣèlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, tí ẹ nfi ipá àti agídí dúró sórí ilẹ̀-onílẹ̀, ilẹ̀ Yorùbá; àti ẹ̀yin tí ẹ pera yín ní Ọba, tí ẹ rò pé ẹ lè máa fa ìdanilórírú (confusion) fún ọmọ Yorùbá, tàbí kí ẹ máa fa yíyà-bàrá (distraction) fún ọmọ Yorùbá, ẹ nkó bá ara yín ni ojoojúmọ́, ìyà yín dẹ̀ npọ̀ si.
Nítorí, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dúró láì yẹsẹ̀, gẹ́gẹ́bí ORÍLẸ̀-ÈDÈ. Orílẹ̀-Èdè ni Yorùbá – kí ẹ jẹ́ kó yé yín – ORÍLẸ̀-ÈDÈ, ibi tí a ti ní ÈDÈ KAN-NÁÀ, ni ilẹ̀ Yorùbá.
Ẹ lọ wádi ní’bi-kí’bi ní àgbáyé. Gbogbo yín tí ẹ nṣe wèrè, tí ẹ nṣe rádaràda ní ilẹ̀ D.R.Y, wèrè máa ṣe yín, torí ilẹ̀-onílẹ̀ lẹ ti nṣe rádaràda yẹn!
Gbogbo àwa ọmọ Yorùbá, ẹ jọ̀wọ́, ibikíbi tí ẹ bá ti ngbọ́ tí wọ́n npè wá ní “ajìjàngbara” (agitator), kí a mọ̀ pé àwọn ọ̀tá Yorùbá ni wọ́n ṣe iṣẹ́ yẹn! Ọ̀dàlẹ̀ ni wọ́n! Kí a jọ̀wọ́ kí a fojú dá irúfẹ́ àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wọ́n dẹ̀ máa jẹ ìyà, wọ́n máa parun.
Ẹ̀yin “Daily Post” tí ẹ kọ ìròyìn àdàmọ̀dì nípa orílẹ̀-èdè Yorùbá, àti akọ̀ròyìn yín, ẹ ò le rùúlà. Ọ̀ràn tí ẹ ẹ̀ lè bọ́ nnú ẹ̀, òun lẹ dá! Tiyín ti bàjẹ́ ní’lẹ̀ Yorùbá. Ẹ̀yin náà lẹ rán àwọn tí ẹ ní ẹ mú, ẹ̀yin náà lẹ tún mú wọn, láti lè da àwọn èèyàn lórí rú.
Ohun tí kò yé gbogbo yín ni pé, àgbáyé ló fi ẹ̀rí sí dídúró tí Yorùbá ti dádúró gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni.
Nítorí ìṣẹ̀dá tí Olódùmarè dá Ìràn àti Ilẹ̀ Yorùbá ni, tí Àjọ-Àgbáyé dẹ̀ jẹ́’rí pé, òtítọ́ ni, orílẹ̀-èdè ni Yorùbá, àti pé kò sí ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe si; bẹ́ẹ̀ ni àgbáyé jẹ́’rí si pé láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí; ni Ìlẹ̀ Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ẹ̀tọ́ àti agbara ìṣèjọba-ara-ẹni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí si pé, kò sí ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe láti yí èyí padà.
Nítorí náà, ẹ wẹ́ gan-an. Ẹ kéré pátápátá, gbáà, nínú ọ̀rọ̀ yí: ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ẹ máa ngba àṣẹ lọ́wọ́ wọn, kí ẹ tó gb’ọ́wọ́ kí ẹ tó gb’ẹsẹ̀! Àwọn babanlá-kú baba-yín tí wọ́n ndarí yín láti ìta: ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ wọn.
Ẹ̀yin tí ẹ nsọ pé ẹ mọ̀ pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dúró, ṣùgbọ́n ẹ nwo ẹni tó máa wá gbé yín jade kúrò ní’bi tí ẹ jẹgàba lé lórí. Ìgbà díẹ̀ ló kù: eré lẹ̀ nṣe: láìpẹ́, láìjìnà, ẹ máa ríran wò. Gbogbo eré géle tẹ́ẹ nṣe la mọ̀.
Dídani-lórí -rú àti kíkọjú-ẹni kúrò l’ọnà (confusion àti distraction) òun lẹ nṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi. Tí ẹ nla ẹnu yín gbàgà máa pè wá ní “agitator”. Ẹ ti ya wèrè: ilẹ̀ Yorùbá ti dádúró! A ti kúrò lára agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Àwọn tí ẹ sọ pé ẹ mú, ẹ̀yin lẹ rán wọn sí’ta, ẹ̀yin náà lẹ lọ mú wọn!
L’ẹyìn ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe ọdún tí a wà yí, ẹnikẹ́ni tó ń ṣe kátikàti, máa tẹ́.