Kì nṣe irin-iṣẹ́ kan péré ni wọ́n fi nṣe’kú pa aláwọ̀dúdú o! Ó tó márun-mẹ́fà bẹ́ẹ̀. Irin-iṣẹ́ wọ̀nyí wà nínú onjẹ, a rí èyí tí ó wà nínú abẹ́rẹ́-àjẹsára, èyí tó wà nínú òògùn-ìwòsàn, èyí tó wà nínú òògùn fún ìtọ́jú ọpọlọ – oríṣiríṣi ọ̀nà, oríṣiríṣi irin-iṣẹ́ ni wọ́n nlò láti ṣe’kú pa aláwọ̀dúdú.
Bóyá ẹ ti máa gbọ́ nípa ayédèrú onjẹ – onjẹ tí wọ́n ti yí ìṣẹ̀dá rẹ̀ padà, eléyi jẹ́ iṣẹ́-ọwọ́ àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀-ti-òyìnbó tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé síta. Wọ́n fi nyí ìṣẹ̀dá onjẹ-oko kúrò ní bí Ọlọ́run ṣe dáa.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, wọ́n ti nyí ìṣẹ̀dá onjẹ́ padà sí èyí tí ó máa ṣe’kú pa àwa aláwọ̀dúdú.
Ọkùnrin tí ó gbé ọ̀rọ̀ yí jáde nínú fọ́nrán náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òyìnbó ni, ó ni òun á sọ òótọ́, torí pé òun ò níí ní àṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ pa ayé run wọ̀nyí; ní pàtàkì, wọ́n fẹ́ pa gbogbo aláwọ̀dúdú pátápátá. Ọkùnrin náà, fùnra-rẹ̀ jẹ́ ògbóntagì onímọ̀-ìjìnlẹ̀-ti-òyìnbó ní ìmọ̀ nípa onjẹ, nítorí náà, ohun tí ó mọ̀ dájú ló nsọ.
Ó pe àwọn kan ní “onímọ̀-ẹ̀rọ-ìṣẹ̀dá” (genetic engineers). Àwọn yí ni wọ́n máa nyí ìṣẹ̀dá ohun àbáláyé padà sí ohun tí ó bá wù wọ́n. Wọ́n lè mú kí onjẹ tàbí ohun-ọ̀gbìn oko kí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn nkan tí ó yàtọ̀ sí bí Ọlọ́run ṣe dá kiní yẹn gan-an gan. Ẹ gbọ́ bí ó ṣe sọ: Ó ní kìí ṣe pé wọ́n lè yí ìṣẹ̀dá erè-oko tàbí ohun-ọ̀gbìn padà nìkan; wọ́n tún lè ṣe é ní ọ̀nà t’ó jẹ́ pé irúfẹ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ kí onjẹ yẹn ṣe ìpalára fún gan-an gan, ni ó máa ṣe ìpalára fún, tí wọ́n bá jẹ ẹ́.
Gẹ́gẹ́bí kí wọ́n yí ìṣẹ̀dá erè-oko padà sí èyí tí ó jẹ́ pé tí aláwọ̀dúdú bá jẹ onjẹ yẹn, ìpalára gidi ló máa fà fun. Ó ní irúfẹ́ ìmọ̀ yẹn ti wà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi. Wọ́n máa npe ètò sáyẹ́nsì-òyìnbó (ìmọ̀-ìjìnlẹ̀-òyìnbó) eléyi ní “RNA Interference Technology.” Òun ni wọ́n fi nṣe iṣẹ́ ibi yí. Wọ́n á yí ìṣẹ̀dá ohun-ọ̀gbìn-oko yẹn padà, kúrò ní bí Ọlọ́run ṣe dáa; bí ó bá ti wá hù, tí a ti kórè rẹ̀, tí ó ti di onjẹ-jíjẹ níwájú wa, tí a nfi sẹ́nu, ìṣẹ̀dá burúkú tí wọ́n fi sínú ẹ̀ yẹn á ṣe ìpalára fún ẹni tí ó jẹ onjẹ́ náà, tí ó bá jẹ́ ènìyàn dúdú ni! Nítorí ìṣẹ̀dá ènìyàn dúdú ní àwọn nkan tó mú wà yàtọ̀ sí ẹ̀yà míràn tí kì nṣe dúdú: nítorí èyí, wọ́n ti mọ bí àwọn ṣe máa yí ìṣẹ̀dá àwọn irúgbìn-oko padà sí èyí tí ó jẹ́ pé tí aláwọ̀dúdú bá ti jẹ onjẹ náà, ni ó máa ṣe iṣẹ́ ibi yẹn ní ara rẹ̀.
Irú ìmọ̀ yí ṣẹ̀ṣẹ̀ wá’yé ni, yàtọ̀ sí ti ayédèrú tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ (GMO). Tuntun ni eléyi, t’ó jẹ́ pé kì nṣe pé ó jẹ́ ayédèrú nìkan, ṣùgbọ́n ayédèrú tí wọ́n ta bí ọfà sí ẹni tí ó jẹ́ aláwọ̀dúdú. Èyí túmọ̀ sí pé, bí ẹni tí kì nṣe aláwọ̀dúdú bá jẹ onjẹ náà, kò ní ṣe ìpalára fun, ṣùgbọ́n tí ó bá ti jẹ́ aláwọ̀dúdú, á paá lára. GMO èyí tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ máa pa ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹẹ́ lára, ìbáà ṣe aláwọ̀dúdú tàbí aláwọ̀ funfun, ṣùgbọ́n tuntun tí wọ́n tún gbé dé yí, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́, kò ní pa wọ́n làra ÀYÀFI tí ó bá jẹ́ aláwọ̀dúdú ni ẹni yẹn. Ìdí tí wọ́n fi ṣe èyí ni pé, wọ́n fẹ́ pa aláwọ̀dúdú, pátápátá, kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
Ọkùnrin òyìnbó yí tún tẹ̀ síwájú, ó ní, Ẹ gbọ́ mi yéké-yéké o! Imọ̀ ìjìnlẹ̀ ti wa lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ sínú erè-oko, onjẹ tí a mú wá láti oko, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ sí irúgbìn rẹ̀ lára tẹ́lẹ̀, t’ó jẹ́ pé, tí ó bá ti jẹ́ aláwọ̀dúdú ló jẹ onjẹ yẹn, wọn ò ní lè bímọ, yálà wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Ṣùgbọ́n tí ẹni tó bá jẹ onjẹ náà kì nbá nṣe aláwọ̀dúdú, kò sí nkan tó máa ṣe ẹni yẹn o! Èyí túmọ̀ sí pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa onjẹ ti wa láyé yí báyi, tó jẹ́ pé ète àwọn ìránṣẹ́ àṣìtáánì tí ó nṣe iṣẹ́ yẹn ni pé àwọn ò fẹ́ ènìyàn DÚDÚ mọ́ ní àgbáyé!
Ọkùnrin òyìnbó yí sọ nínú fọ́nrán èkíní tí a gbọ́ l’aná pé wọn ò kì ngbé ìròhìn nípa ìmọ̀ yí síta nínú àwọn ilé-iṣẹ́ ìròhìn ti ìjọba tàbí ti aládani tí ó jẹ́ aládanlá! Wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ pé kí àwọn aláwọ̀dúdú máṣe mọ̀ pé àwọn alágbayé wọ̀nyí fẹ́ pa ènìyàn dúdú run.
Ọkùnrin yí wá sọ o, pé ìjọba ilú Amẹ́ríkà gan-an gan ni ó nbá wọn fi ọwọ́ bo ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀, àwọn gan-an ni olùgbọ̀wọ́ iṣẹ́ ibi yí! Ó sọ pé ó ní iṣẹ́ ibi tí àwọn àjọ tó sọ pé àwọn ndẹ́kun àjàkálẹ̀-àrùn ní Amẹ́ríkà (CDC), ó ní iṣẹ́ ibi tí wọ́n nfi abẹ́rẹ́-àjẹsára ṣe fún àwọn ọmọ-wẹ́wẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀dúdú, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ìjọba wọn kò jẹ́ kí àwọn ará-ìlú ó mọ̀ pé nkan yẹn nṣèlẹ̀.
Ìjọba Amẹ́ríkà kan-náà yí ni wọ́n nfi owó ará-ìlú ṣe onígbọ̀wọ́ fún ṣíṣẹ́-oyún àwọn aláwọ̀dúdú-ọmọ tí ó ṣì wà nínú ìyá wọn – wọ́n a sọ pé ìfètò-sọ́mọ-bíbí l’àwọn nṣe, ṣùgbọ́n àwọn oyún ọmọ-aláwọ̀dúdú gan-an gan ni wọ́n d’ojú kọ fún ṣíṣẹ́.
Ìjọba Amẹ́ríkà kan-náà yí ni wọ́n nṣe nkan ìpalára sínú omi tó nlọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà gan-an gan tí wọn ò kì nṣe òyìnbó ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ibẹ̀ ni òyìnbó bá wọn, tí wọ́n tẹ orí wọn ba.
Ijọba kan-náà yí ni wọ́n fẹ́ lo àjọ FBI wọn l’ọjọ́-un l’ọhún pé kí Martin Luther King Junior, akọni-ènìyàn-dúdú tí ó njà fún ẹ̀tọ́ aláwọ̀dúdú, tí wọ́n fẹ́ jẹ́ kó pa ara rẹ̀.
Ìjọba-Amẹ́ríkà gb’ogun tì yín, ẹ̀yin aláwọ̀dúdú, kí ẹ yára mọ̀ báyi. Ọ̀tá ni ẹ jẹ́ lójú ìjọba Amẹ́ríkà, wọ́n nṣe oríṣiríṣi lójoojúmọ́ láti pa’yín run, wọn ò fẹ́ rí aláwọ̀dúdú kankan lórí ilẹ̀. Àwọn ìjọba yí ni wọ́n dẹ̀ ngbé owó sílẹ̀ fún àwọn oní’wadí ìjìnlẹ̀-sáyẹ́nsì, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọn ò ní gbé owó sílẹ̀, láyé, fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣe ìwádi láti gbé òótọ́ yí síta pé ṣé bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ mọ̀ọ́-mọ̀ tàbí wọ́n nmọ̀ọ́-mọ̀ pa aláwọ̀dúdú láti pa-wọ́n-run.
Wọ́n máa fọwọ́ bòó mọ́’lẹ̀ ni, tí ẹnikẹ́ni kò níí mọ̀ pé ète àti iṣẹ́ ti nlọ láti mú ìrántí aláwọ̀dúdú kúrò ní ayé yí. Ó pẹ́ tí wọ́n ti nf’ọwọ́ bo oríṣiríṣi iṣẹ́ ibi mọ́’lẹ̀, ìyẹn kì nṣe nkan ọ̀tun, ó kàn jẹ́ pé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí wọ́n fi nṣe-é ti wá ng’òkè-àgbà si. Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ti wà báyi tí wọ́n nlò kí aláwọ̀dúdú máṣe lè bímọ, tàbí kí oyún ó máa bàjẹ́ mọ́ wọn lára-léra-léra!
Ẹ̀yin aláwọ̀dúdú, ẹ tún gbọ dáadáa, wọ́n d’ojúkọ’yín gidi, láti pa yín run [ọ̀rọ̀ tí ọkùnrin òyìnbó onímọ̀-ìjìnlẹ̀ yí sọ jáde ni’yí].
Ó tún sọ̀rọ̀ síwájú, ó ní, L’oótọ, gbogbo àwa ènìyàn ni àwọn oníṣẹ́-ibi wọ̀nyí ndojú-ìjà kọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ aláwọ̀dúdú gan-an gan ni wọ́n fẹ́ parun pátápátá kí ẹ má tilẹ̀ sí lórí ilẹ̀ ayé mọ́.
Ó ní, ibi tí wàhálà wà gangan ni gbígbé ìgbé-ayé ọmọ ènìyàn lé ọwọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ òyìnbó (sáyẹ́nsì) àti ètò-ìwòsàn òyìnbó (medicine). Ó ní wàhálà tí ó wà ni pé àwọn “alágbayé” wọ̀nyí, tí wọ́n fẹ́ dín iye ènìyàn tí ó wà ní àgbáyé kù, wọ́n ti mú gbogbo nkan tí a npè ní “sáyẹ́nsì” ní ìgbèkùn sí abẹ́ àkóso tiwọn, kí sáyẹ́nsì máa ṣe iṣẹ́ tí àwọn bá ti ran nìkan!
Sáyẹ́nsì kò lè sáyẹ́nsì fún’ra rẹ̀ mọ́. Inkan tí àwọn alágbayé wọ̀nyí bá ti ní kí sáyẹ́nsì ó gbé jáde, tàbí kí ó sọ, ni sáyẹ́nsì máa sọ! Àwọn èèyàn ò dẹ̀ mọ̀, wọ́n á sọ pé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì ní ó gbé kiní ọ̀ún jáde, nítorí-náà, ó níláti jẹ́ òótọ́! – láì mọ̀ pé sáyẹ́nsì gan-an gan kọ́ ló-nfọ’hùn! – àwọn alágbáyé wọ̀nyí ní ó ngbé ìfẹ́ tiwọn sí ta, láti dín ènìyàn kù ní àgbáyé, pàápàá láti pa aláwọ̀dúdú run pátápátá, ṣùgbọ́n wọ́n á lúgọ sábẹ́ sáyẹ́nsì (ìmọ̀-ìjìnlẹ̀-òyìnbó), wọ́n á ní sáyẹ́nsì ló gbé kíni yẹn síta pé onjẹ báyi ló yẹ kí ẹ máa jẹ; abẹ́rẹ́-àjẹsára báyi l’ẹ gbọ́dọ̀ gbà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, irọ́ dẹ̀ ni – àwọn alágbayé wọ̀nyí ni wọ́n nsá-pamọ́ sábẹ́ sáyẹ́nsì ṣe iṣẹ́ ibi wọn; ṣùgbọ́n àwọn ará-ìlú ò ní lè fún’ra wọn ṣe ìwádi sáyẹ́nsì tiwọn fúnra wọn, torí ìjọba ti gba àkóso ibẹ̀ yẹn – àwọn ni wọ́n ni irúfẹ́ gbigbé owó bẹ́ẹ̀-yẹn kalẹ̀.
Ọkùnrin yí wá sọ̀rọ̀ báyi, ó ní, gbogbo wa ti wá wà nínú oko-ẹrú sáyẹ́nsì-irọ́ tí wọ́n fi nkó wa l’omi ọbẹ̀ jẹ. Ó ní, a wà lábẹ́ amúnisìn, tí orúkọ amúnisìn ọ̀ún dẹ̀ njẹ́ “sáyẹ́nsì” (ìmọ̀-ìjìnlẹ̀-òyìnbó). Ó ní, “sáyẹ́nsì ti kó gbogbo wa lẹ́rú.” Ìnkan t’a bá ṣáà ti gbọ́ pé sáyẹ́nsì ló gbe jáde, àá ṣáá máa tẹ̀le gọ̀ṣú gọ̀ṣú. Ó ní, bí ọ̀rọ̀ wa ṣe rí l’oní gan-an gan nìyẹn – a wà ní oko-ẹrú sáyẹ́nsì!
Ọkùnrin onímọ̀-ìjìnlẹ̀ yí sọ báyi pé, “Àwọn ará’bí yíìí, kọ̀ láti sọ òtítọ́ fún wa, ṣùgbọ́n wọ́n ngbógun ti àwọn èèyàn wa, àti àwọn ọmọ, ọmọ-ọmọ wa, láti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn nkan tí wọ́n dẹ̀ nlò, láti ṣe iṣẹ́ ìṣe’kú-pa’ni wọ̀nyí ni – òògùn tí wọ́n ngbé jáde fún wa pé kí a máa lo, onjẹ tí wọ́n ngbé jáde fún wa pé kí a máa jẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Ó wá tún sọ o, ó ní ọ̀rọ̀ tí òun sọ yí gan-an gan ni ìṣoro tí a ní – pé kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ sáyẹ́nsì sínú òkùnkùn fún wa, kí wọ́n máa purọ́ fún wa, wọ́n á dẹ̀ sọ pé sáyẹ́nsì ló gbé nkan ọ̀ún jáde, tí kò dẹ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ó wá sọ pé, a nílò ìwádì sáyẹ́nsì tí àwa fún’ra wa máa ṣe, tí ó dá wa lójú; kìí ṣe eléyí tí àwọn kan ṣe nínú òkùnkùn, pẹ̀lú àtilẹhìn àwọn ìjọba onírọ́, tí wọ́n á wá máa gbé irọ́ wọn síta, pé òun ni kí a máa tẹ̀lé!
Ó sọ báyi, ó ní, A nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ yàrá-ìwádi-sáyẹ́nsì bí irú tèmi yí, tí ó jẹ́ pé mi ò gba owó láti ọ̀dọ̀ ìjọba fún iṣẹ́-ìwádi tí mo nṣe níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tí mo ṣe lè sọ òtítọ́ yí fún yín. Ṣé ẹ rò pé tó bá jẹ́ pé àwọn ilé-iṣẹ́ nlá kan ló nfún mi lówó, tí ó dẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ìjọba l’àwọn gan-an ti ngba owó yẹn, ṣé ẹ rò pé màá ní ẹnu-ọ̀rọ̀ láti sọ nkan wọ̀nyí fún yín ní? Láyé! Ní tèmi, èmi ò níí gba owó l’at’ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ àṣìtáánì, tí wọ́n nṣe’kú pa yín. Mí ò níí gba owó lọ́wọ́ ìjọba apànìyàn. Ìjọba apànìyàn ni ìjọba Amẹ́ríkà.
Àwọn CDC (àjọ tó nbojútó dídẹ́kun àjàkálẹ̀-àrùn ní Amẹ́ríkà), FDA (àjọ tó nrí sí ìpèsè onjẹ àti òògùn), EPA (àjọ tí ó nrísí ààbò àyíká) – wọ́n kàn gb’orúkọ lérí ni, gbogbo wọn PÁTÁ ni wọ́n jọ lọ́wọ́ nínú ètò ìṣekúpa ọmọ aráyé yí, pàápàá ìṣekúpa aláwọ̀dúdú. Ó dẹ̀ ti wà bẹ́ẹ̀ tipẹ́! Iṣẹ́ wọn ni kí wọ́n máa kó àrùn bá èèyàn, kí ọpọlọ yín ó ní ìpalára, kí ọmọ tí ẹ bá nbí ó ya dìndìnrìn. Àfi ìgbà tí àwa ará-ìlú fún’ra wa bá dìde; kí á gbà òmìnira ìgbésí-ayé wa padà; wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀! Wọ́n npa ọmọ-ènìyàn, wọ́n npa odiidi-ìràn run, ṣùgbọ́n wọ́n npèé ní àgbéjáde ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ (sáyẹ́nsì), wọ́n tún npèé ní àgbéjáde ìmọ̀-ìwòsàn (medicine).
Ó wá sọ pé “A níláti jẹ́ kí àwọn èèyàn ó mọ bóṣe-nlọ! Kí wọ́n máṣe wà nínú òkùnkùn mọ́.
Ó ní, Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bá mí gbé ọ̀rọ̀ yí sita; ẹ bá mi pin káàkiri. Onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ni èmi tí mo sọ ọ̀rọ̀ yí fún yín, ṣùgbọ́n mi ò sí lára àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tí wọ́n fi owó dí lẹ́nu! Mo mọ gbogbo ìwà ibi tí ó nṣẹlẹ̀, mo dẹ̀ pinu pé, mi ò ní pa ẹnu mi mọ́; mo pinu láti SỌ̀RỌ̀ síta! Wọ́n á máa pa ọmọ-ènìyàn, wọ́n á fi sáyẹ́nsì bo’jú! Aláwọ̀dúdú ni wọ́n dẹ̀ dojú kọ. Wọ́n fẹ́ kí ó máṣe sí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláwọ̀dúdú mọ́ ní àgbáyé yí.
Èyí ni òpin ọ̀rọ̀ tí ọkùnrin òyìnbó yí sọ.
Àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ẹ wá jẹ́ kí á bá ara wa sọ̀rọ̀ báyi. Ṣé a ti wá rí bí ayé yí ṣe rí? Kí a máṣe ró pé ààbò wà fún wa ní ibikíbi, yàtọ̀ sí Olódùmarè. Kì dẹ̀ nṣe kí á káwọ́ gbera sọ pé Ọlọ́run á ṣeé. Ọ̀nà tí Ọlọ́run ti f’ẹsẹ̀ wa lé yí, ni kí á máa tọ̀. Olùgbàlà tí ó jẹ́ Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí wa, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, kí á dúró ti òtítọ́ tí wọn gbé dání.
Ṣé ó ti wá yé wa báyi, ìdí tí wọ́n fi gbé GMO wá? Láti ṣe’kú pa’ni. Àwọn àgbẹ̀ t’ó ní irúgbìn àbáláyé dání, àwọn ni wọ́n npa, tí a kàn nrò pé àwọn darandaran kan ló nṣe iṣẹ́ yẹn, ṣùgbọ́n àwọn alágbayé yí ló rán àwọn darandaran. Ṣé ó ti nyé wa! Tí wọ́n bá ti ní kí a má gba abẹ́rẹ́ àjẹsára, ṣé ó ti yé wa báyi ìdí tí a nílati ṣe ìgbọ́ran!?
Èkíní nínú àwọn fọ́nrán tí a gbọ́ l’aná ni a mú àlàyé rẹ̀ wá fún wa lóni. Márun ni àwọn fọ́nran yẹn, ojoojúmọ́ ni a máa máa mú ìkọ̀ọ̀kan wá, títí di ọjọ́ ẹtì, bẹ́ẹ̀ ni ìròyìn pàtakì yí yíò máa wáyé láti ìgbà dé ìgbà. Ìròhìn Òmìnira IYPDRY ló mu wá sí etí-ìgbọ́ wa.