ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
Ìjọba aláìlọ́pọlọ tí ó wà ní Nàìjíríà tún ti fi ìwà dìndìnrìn wọn hàn. Ajá tó máa sọnù, tí kò gbọ́ fèrè ọdẹ ni wọ́n – ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ ṣetí bí ẹni tí kò gbọ́ran! Ayé yín kúkú ti pòórá kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá, ẹ̀ẹ́ tó fojú ara yín ri.
Ìròyìn tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, X, fi hàn pé ní Orílẹ̀-Èdè wa (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ní Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́, ní agbègbè Yagba, ni a gbọ́ pé ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà sọ pé àwọn ti mú ènìyàn méjé tí wọ́n nwa kùsà láìní àṣẹ. Àṣẹ tani o? Ẹ bá wa bérè lọ́wọ́ wọn! Ṣé agbègbè Yagba jọ ilẹ̀ Nàìjíríà, àbí orí yín ti dàrú?
Tinubú, sọ fún wèrè Aláké kó mójú kúrò lára Orílẹ̀-Èdè Yorùbá! Ilẹ̀ agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kò dé Yagba, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni Yagba wà o!
ÌA ti nkígbe báyi, ajẹgàba Nàìjíríà, pé kí ẹ kó àwọn ajá yín kúrò ní ibi gbogbo àti ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti D.R.Y, ṣùgbọ́n ìparun kíkorò tí ó máa dé bá yín kò jẹ́ kí ẹ gbọ́! A ò bẹ̀ yín ní’ṣẹ́ kí ẹ bá wa lé ẹni tó nwa kùsà lórí ilẹ̀ wa; a ní ètò tiwa láti ṣe iṣẹ́ lóri gbogbo nkan tó jẹ́ tiwa. A ò nílò ìrànlọ́wọ́ agbésùnmọ̀mí, ẹ̀yin ajẹgàba tí ó máa parun láìpẹ́ yí. Ìfarahàn ìdájọ́ yín ti dé ná, ẹ̀ẹ́ tóó mọ̀!