Nínú ohun gbogbo, ẹ jẹ́ kí a máa bẹ̀rù Ọlọ́run, àwọn tí ìrẹ̀ wọ́n yó tán, tó wá ní kí wọ́n fi kété tú ìfun òun, ni ọ̀rọ̀ àwọn tí a fẹ́ sun jẹ, tí wọ́n wá fi epo para, wọ́n bá lọ jókòó ní ẹ̀yìn ààrò; òun ní ọ̀rọ̀ àwọn agbéraga tí wọ́n pé’ra wọn ní ọba ní ilẹ̀ Yorùbá; àwọn tí ó yẹ kí wọ́n f’orí pamọ́, kí wọ́n sì máa ra’wọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè pé, kí ó dárí àṣìṣe wọn jìn wọ́n, ṣùgbọ́n, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n tún ń dá ọ̀ràn mọ́ ọ̀ràn.
Ìròyìn kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, ni kìí ṣe àjèjì sí wa, ṣùgbọ́n, ó fi hàn kedere pé, wọn kò ní àyípadà ọkàn ju kí wọ́n máa ṣe ibi wọn lọ síwájú sí i. Ó dájú pé, ẹni tí ó bá ti ń bá Ọlọ́run fi iga gbá ‘ga, ìparun rẹ̀ tí wà ní ẹ̀yìn ọrùn rẹ̀.
Ọ̀kan lára awon tó ṣì ń pe’ra wọn ní ọba ní ìlú Eko, Adeniyi Ajayi, ni ó yó tán, ó ní pé, kò si ohun tí Ọlọ́run pàápàá le ṣe fun òun lórí ilé àti ilẹ̀ ẹni tí kò ní agbára, tí òun wa ń fi ọwọ́ ọlá gbá lójú, tí ó sì gba ilẹ̀ náà, tí ó tún wó ilé orí rẹ̀, ilẹ̀ tí oní-nkan ti rà láti ọdún mẹ́rin-lé-lógún sẹ́yìn. A ríi nínú àwòrán tí wọn ti da ilé náà wó lulẹ̀.
Ìròyìn náà sọ pé obìnrin tí ó ni ilẹ̀ yí ti lé ní àádọ́rin-ọdún lọ́jọ́ orí. Ẹ̀yin kan wá ń fi owó b’ayé jẹ́, ẹ kì í kúkú ṣe ọba orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), nítorí àwa kò ní ọba ní ilẹ̀ wa, àwọn ọba tí wọn ń fi ogun ja àwọn tí wọn ní àwọn jọba lé lórí.
A ò mọ ohun tí ẹ gbójúlé, tí ó ń mú inú yín dùn lórí àwọn ìwà ìkà tí ẹ ń hù sí àwa ọmọ Aládé, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa jẹ’wọ́ Ara Rẹ̀ fún yín láìpẹ́.