Orílẹ̀ èdè Burundi gba àlejò òjijì ààrùn kan tí wọ́n ń pè ní MPOX tí wọ́n ńkó láti ara ẹranko ọ̀bọ. Àjàkálẹ̀ àrùn yí máa ń farahàn bí ifọ̀n ní ara ènìyàn, ó sì máa tètè ràn yíká ní àárín ènìyàn. Èyí jẹ́ ohun ìdààmú fún orílẹ̀-èdè Burundi nítorí ó jé ọ̀kan nínú orílẹ̀-èdè tí kò ní àlùmọ́ọ́nì púpọ̀.
A ríi nínú ìròyìn tó gbe jáde pé ibùdó kan ṣoṣo ni ó wà fún àyẹ̀wò pàjáwìrí láti mọ̀ ẹnití ó bá ti kó àrùn yìí, tàbí fún gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà ààrùn nàá. Bákannáà sì ni ó rí ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà tẹ́lẹ̀, tí kò ní ibití wọ́n ti lè máa ṣe àyẹwò tàbí gba ìtọ́jú pèlú, kí ààrùn náà tó wọra.
Ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, tí Olódùmarè ti lo màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti gba wa kúrò nínú ìgbèkùn àsopọ̀ pẹ̀lù agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, tí ìṣèjọba wa sì bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún o le mẹrinlelogun nígbàtí a búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́, a ti ní ètò sílẹ̀ láti leè kojú àjàkálẹ̀ ààrùn ti ó bá wọlé sí orilẹ èdè Yorùbá nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé màmá wa lọ́wọ́, a ó padà sí ọ̀nà tí àwọn babańlá wa ńlò láti ṣe ìwòsàn nípa lílo èwe àti egbò, kò sì irú àìsàn náà ní ayé yìí tí àwọn bàbá wa kò leè wò, bẹ́ẹ̀ sì ni ètò ìwòsàn ọfé wà fún àwọn àgbà àti èwe ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ní àwọn ilé ìwòsàn wa.
Kété tí a bá ti lé àwọn ajẹgàba ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria kúrò lórí ilẹ̀ wa, àwọn Adelè wa yóò wọ ìlé iṣẹ́ ìjọba láti tẹ̀síwájú fún ìfarahàn iṣẹ́ tí wọ́n tí ń ṣe. Àsìkò yìí kò pẹ́ mọ́ rárá. Ní àfikún ìlera ará ìlú jẹ́ dandan fún ìjọba orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé , “Ìlera ní oògùn ọrọ̀.”