OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYIOLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà, pé a ò níí ti oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn! Wọ́n sọ èyí nítorí pé, Olódùmarè ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àṣìrí ní àgbáyé han wọ́n, èyí tí ó wá wúlò nínú iṣẹ́ ìgbàlà tí Ẹlẹ́da rán wọ́n, fún ìṣerere Ìran Yorùbá.

Òtítọ́ pàtàkì ni pé, orílẹ̀-èdè tí ó bá dá Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) mọ̀, ni àwa náà máa dá-mọ̀ gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè.Orílẹ̀-èdè tí ó bá pọ́n wa lé, ni àwa náà máa pọ́n-lé.

Orílẹ̀-èdè tí ó bá bu ọ̀wọ̀ fún wa ni àwa náà máà bu ọ̀wọ̀ fún.Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́bí MOA ti sọ, D.R.Y kò ní ṣe ẹrú fún orílẹ̀-èdè kankan ní àgbáyé!

Ojú tí orílẹ̀-èdè k’orílẹ̀-èdè bá fi wò wá, ni àwa náà máa fi wò ó!Bẹ́ẹ̀ náà ni a ò ní bá orílẹ̀-èdè kankan pàdípọ̀ máa b’ẹnu àtẹ́ lu orílẹ̀-èdè míràn!

A ò ní bá wọn gbè s’ẹyìn orílẹ̀-èdè kan ṣe lòdì sí òmíran, àbí kó ọ̀wọ́-àbòsí pẹ̀lú orílẹ̀-èdè kan tako orílẹ̀-èdè míràn.Paríparì gbogbo rẹ̀, ohun tí ó jẹ́ atọ́kùn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tí ìbáà-wù kó jẹ́, ni pé, L’ẹyìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá Ni Àkọ́kọ́!

A ò ní ta ohunk’ohun ní rọ̀bì fún orílẹ̀-èdè míràn. Ohun tí a bá ma tà jáde, jẹ́ ohun tí a ti sọ di oníye-lórí, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní fi orílẹ̀-èdè wa sílẹ̀ máa wá ohun-ìmúlò fún àwọn ilé-iṣẹ́ wa ní’bi tí kò tọ́.

Irúfẹ́ ìgbésẹ̀-akin wọ̀nyí, kò ní fi àyè gba orílẹ̀-èdè kankan láti fi ìwọ̀sí lọ D.R.Y abí Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), bẹ́ẹ̀ ni a ò ní kó ara wa sí àfọwọ́-fà burúkú kankan!