A rí ìròyìn kan kà lórí ẹ̀rọ ayélujára X, bí Seyi, ọmọ Tinubu, ṣe ní ilé iṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ̀ rẹ̀ Lebanese, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Ronald Chagoury.
Èyí kìí ṣe èèwọ̀. Ṣùgbọ́n ọmọ Chagoury yí tún ní ilé-iṣẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Hightech Construction, èyí tí ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó njẹgàba lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) gbé àdéhùn agbaṣẹ́ṣe iṣẹ́ ojú-òpópónà ńlá kan tí wọ́n sọ pé yíò lọ láti ilu Èkó sí Calabar fún, ní bílíọ̀nù mẹ́tàlá dọ́là, láìsí Èkó nínú Nàijíríà! Ibẹ̀ ni wàhálà ti wá wà o!
Báwo ni ti Èkó ṣe jẹ́? Èkó kìí se ara Nàìjíríà mọ́, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún; pàápàá, a ti ní ìjọba tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, nígbàtí a di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, Democratic Republic of the Yoruba, èyí tí Èkó wà nínú rẹ̀.
Nítorí náà, ìkọjá-àyè gbáà ni, ọ̀ràn nlá gbáà sì tún ní lábẹ́ òfin àgbáyé, kí Nàìjíríà ó máa ka ilẹ̀ Èkó mọ́ ibi tí àwọn fẹ́ ṣe pópónà gbà, àbí irú àrífín àti ìjẹgàba wo nìyẹn?
Nàìjíríà, a nkì ẹ́ nílọ̀! Jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa Democratic Republic of the Yorùbá! Ago ìdájọ́ rẹ ti kún o! O dẹ̀ máa tẹ́!
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ẹni tí Ẹlẹ́da Ìran Yorùbá lò, láti lè jẹ́ kí àwa ọmọ Yorùbá lẹ́nu ọ̀rọ̀ ní ìkóríta tí a dé yí, tí a fi lè máa sọ wípé, Nàìjíríà jáde kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y !