Ní’gbà tí Olóyè MKO Abíọ́lá kú, ní ọjọ́ kéje, oṣù kéje, ọdún 1998, a mọ̀ wípé wọ́n fun ní tea mu, Susan Rice, òṣ’iṣẹ́ fún ìjọba America sì pẹ̀lú àwọn tí wọn jọ wa ní’bẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìjọba ol’ógun Nigeria.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí.Olori Adele Orílẹ̀-Èdè Yorùbá,
Ọgbeni Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkore
A kìí ṣe ọmọdé, bẹ́ẹ̀ ni a kìí ṣe ọ̀dẹ̀; kò s’ẹni bé’rè ẹjọ́ l’ọwọ́ Susan Rice, èyí tí ó fi wá nsọ mọ́namọ̀na nínú ìwé itan ìgbésí ayé rẹ̀ wípé kìí ṣe ni wọ́n pa Abíọ́lá.
Ó ṣeun gan-an ni o, a ò bérè ẹjọ́ l’ọwọ́ rẹ̀ rárá.
Nṣe ni k’ó kó gbogbo wàhálà t’ó dé báa ẹ kúrò ní sàkání tiwa.
Ka Ìròyìn: Àwọn Òyìnbó, Aláyébàjẹ́ Ni Wọ́n
Ìwọ kọ́ l’ó máa sọ ìtàn bí Abíọ́lá ṣe kú fún’wa. A ní ìtàn ti’wa nípa bí wọ́n ṣe pa Abíọ́lá.
Ayé àtijọ́ ni òyínbó ti máa np’ìtàn ìran Yorùbá fún Yorùbá. Ní’si’ìyí, aṣọ ìbòjú ti kúrò l’ojú wa; ati wá kúrò l’oko ẹrú pátápátá l’abẹ́ òyìnbó.
Aláìnítìjú t’ó nsá pamọ́ s’ẹhìn ìka kan.
Ka Ìròyìn: Tí o bá fẹ́ sọ ẹ̀yàk’ẹyà di ẹrú, gba èdè àti ìtàn wọn – Wendall Donelson