Ní ìkóríta t’a dé yí, ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á bá ara wa sọ àwọn géndé ọ̀rọ̀ kan. Gbogbo wa, gẹ́gẹ́bí ọmọ rere, ojúl’owó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ni a fẹ́ ohun rere fún ìgbádùn ìgbésí ayé wa.
Àkókò mélo ni a fẹ́ lò l’ayé, tí a bá ní kí á fi ojú ara wòó; àkókò mélo l’a fẹ́ lò l’ayé, tí a máa máa fi ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rin ìgboro ayé yí, bí ẹni tí ó bá wọn wá’yé, tí kò ní le rìn fanda, fanda, tí kò sì ní ní ìgbádùn kankan rárá nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Tàbí nṣe l’o kàn sìn wọ́n wá’yé ni.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí.
Olori Adele, D.R.Y
Tí ó bá jẹ́ wípé kìí ṣe ni o kàn sìn wọ́n wá’yé, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé nṣe l’o wá’yé tìrẹ ní gidi; ó ṣe pàtàkì l’ọpọ̀l’ọpọ̀ kí o káràmásìkí ilé ayé tí o wá. Olódùmarè ti fún’ra rẹ̀ dá ọ ní Yorùbá; ó wá kù sí ẹ l’ọwọ́ l’ati ri dá’jú wípé o rí’lé ayé wá!
Báwo ni a ṣe nṣe eléyi? L’ọnà kíní, o níláti ri dá’jú wípé o kò kọ ìran rẹ sí’lẹ̀, ìran Yorùbá.
Ka Ìròyìn: Revive Us Olódùmarè – Indigenous Yoruba People Prays to God Almighty
Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ l’ó jẹ́ wípé ìran wọn kò jẹ wọ́n l’ogún rárárárá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé ayé òyìnbo, ayé ‘alákọ̀wé’ ti yí wọn l’orí; tí wọ́n sì rò wípé ọ̀làjú ni irúfẹ́ ìgbésí-ayé bẹ́ẹ̀ já sí; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n kó’ríra ohun tí ó jẹ́ ti Yorùbá; kódà, nkan náà ṣe wọ́n dé’bi wípé wọn kò ti’lẹ̀ mọ̀ wípé ìran tí Olódùmarè dá wọn ṣe pàtàkì rárá.
Wọ́n rò wípé tí a bá ṣáà ti rí onjẹ jẹ, ìyẹn l’ó tú’mọ̀ sí wípé a ti rí ilé ayé wá. Wọn kò mọ ìtú’mọ̀ ohun tí a npè ní ìran; tí àwọn bá ṣáà ti rí owó ná; wọ́n rò wípé ìyẹn nìkan ni ayé.
Wọ́n tún wá yà’tọ̀ sí àwọn tí ó jẹ́ wípé, owó pàápàá wọn kò ní; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ̀ wípé, àt’ẹni tí kò ní, àt’ẹni t’ó ní ṣùgbọ́n, sí’bẹ̀, kò náání ìran rẹ̀, àt’èkíní àt’èkejì, ni wọ́n níl’ati mọ rírì ìran tí Olódùmarè dá ẹn’ìkọ̀ọ̀kan sí.
Ìwọ gẹ́gẹ́bí Yorùbá, yálà o l’owó ni, tàbí o kòì tíì ni, óò ní’bi kankan írè ní ilé ayé yí tí o kò bá bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ pẹ̀lú fífi ọkàn sí orí’sun rẹ; èyíinì, Ìran tí Olódùmarè dá ọ mọ́.
Ka Ìròyìn: After God Almighty, Think Yorùbá First
Kíni ìdí èyí? ìdí rẹ̀ ni wípé, ohun kan wà tí a npè ní Ìṣẹ̀dá. Ìṣẹ̀dá jẹ́ ohun tí a kò leè dà; tí a bá da ìṣẹ̀dá wa; ìṣẹ̀dá ọ̀hún a máa wo’ni ní’ran; ìṣẹ̀dá sì ti mọ̀ wípé, bí o re òkun, bí o re ọ̀sà, tí o kò bá padà s’ọdọ̀ òun ìṣ’ẹ̀dá rẹ, o kòì tíì le mú kádàrá rẹ, tàbí àyànmá àmút’ọ̀run rẹ ṣẹ ní’lé àyé.
Nítorí èyí, ìṣẹ̀dá wa gẹ́gẹ́bí Yorùbá ṣe pàtàkì l’ọpọ̀l’ọpọ̀; kò sì sí ohun tí a lè ṣe ní àṣeyọ’rí, gidi, gẹ́gẹ́bí Olódùmarè ṣe fẹ, láì jẹ́ wípé a ṣeé ní ìbámu pẹ̀lú ìṣ’ẹ̀dá wa.
Èyí túmọ̀ sí wípé, pẹ̀lú ìbámu pẹ̀lú ìṣ’ẹ̀dá ìran wa, ìran Yorùbá; nít’orí wípé ìṣ’ẹ̀dá wa ti bẹ̀rẹ̀ l’ati ìṣ’ẹ̀dá Ìran wa.
Àwa gẹ́gẹ́bí Yorùbá, ayé wa kò lè rí gẹ́gẹ́bí Olódùmarè ṣe fẹ́ k’ó rí, tí ìran Yorùbá, l’akọ́kọ́, kò bá rí bí Olódùmarè ṣe fẹ́ k’ó rí.
Ka Ìròyìn: Má Ṣe Gb’ara Lé Ọmọ Íbò, Ẹni ibi Ọ̀dàlẹ̀ Ìran Níwọ̀n
Ìṣ’ẹ̀dá ìran kọ̀ọ̀kan yà’tọ̀ sí ara wọn. Ìwọ gẹ́gẹ́bí Yorùbá, ayé rẹ kò le rí gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè ṣe fẹ́ k’ó rí gan-an gan, tí o bá ngb’ìyànjú l’ati gbé ìgbé ayé náà gẹ́gẹ́bí, tàbí, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣ’ẹ̀dá Gẹ̀ẹ́sì; bẹ́ẹ̀ ni ìgbé-ayé ọmọ Ìgbò kò lè rí bí ó ṣe yẹ k’ó rí, tí ó bá ngb’ìyànjú l’ati gbé ìgbé-ayé náà gẹ́gẹ́bí ìṣ’ẹ̀dá Potogí àbí gẹ́gẹ́bí ìṣ’ẹ̀dá Yorùbá. Kò bá’ra mu rárá.
Ìdí ni’yí tí a níl’ati b’o’jútó ohun tí ó bá ìṣ’ẹ̀dá wa mu; èyíinì, kí á b’ojútó ohun tí ó jẹ́ ti ìran Yorùbá, nítorí ìran tí Olódùmarè dá wa mọ́ n’ìyẹn; ìṣ’ẹ̀dá Yorùbá l’ó sì wà l’ara wa.