Èyí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìkórira òyìnbó, ṣùgbọn, tí a kò bá ní tan ara wa jẹ, a níl’ati jẹ́ kí a mọ oríṣiríṣi ohun ibi tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí nṣe sí ọmọ ènìyàn àti sí gbogbo àyé.
Ní àípẹ́ yi ni òṣìṣẹ́ ètò ìwòsan kan tí òun fún’ra rẹ̀ jẹ́ òyìnbó, ni ó sọ, tí a sì gbọ́ l’ori TikTok, wípé, wọ́n máa nfi àwọn omi (chemical) olóró ránṣẹ́ sí àwọn ilé-iṣẹ́ nlánlá tí ó npo òògùn l’agbáyé (èyíinì, pharmacy), tí àwọn yẹn náà á sì wá pòó mọ́ ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn òògùn-bí-onjẹ (supplements), àti sí’nú àwọn oríṣiríṣi ohun bí ẹran jíjẹ (protein), bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n nfi sí’nú àwọn ohun-mímu-àmúṣ’agbára (energy drink) àti sí’nú àwọn èròjà am’ara-le-koko (vitamin) tí wọ́n ntà sí ìgboro ayé!
Níbó ni wọ́n ti máa nri àwọn ohun olóró wọ̀nyi?
Ọkùnrin yí sọ wípé l’ara ibi tí wọ́n bá ti sọ wípé àwọn nyí ìdọ̀tí ilé-ìgbẹ́ tí wọ́n ti kó lọ, ni wọ́n ti ni ohun tí wọ́n máa nṣe síi l’ati mú nkan olóró já’de ní’bẹ̀. Ó pe ìkan nínú àwọn ohun olóró wọ̀nyí ní Hydrogen Cyanide.
Nítórí èyí, ọkùnrin yí sọ wípé ohunk’ohun bí òògùn-bí-onjẹ (supplements) tí o bá ní sí’lé, wo ara ike rẹ̀ dáradára; tí o bá ti ri wípé cyanochobalamin (bẹ́ẹ̀ni, cyanochobalamin), tí o bá ti ri wípé ó pẹ̀lú àwọn nkan tí wọ́n pò pọ̀ l’ati fi ṣé, nṣe ni kí o yá’ra jùú sọ nù!