Tí o bá wà níbí ní Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n o wá láti Áfríkà, láti Asia, tàbí ibikíbi yíò wù kó jẹ́ ní àgbáyé, tí o ò sí ní àwọn ìwé tí ó yẹ kí o ní, ó ṣeni ní àánú pé mo ní láti sọ fún ẹ, padà sílé, padà síbi tóo ti wá, padà síbi ìṣẹ̀dálẹ̀ tìrẹ.

Mi ò kórira ìlú yín o, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ìlú yẹn ni mo ti ṣòwò níbẹ̀ rí, mo mọ̀ wọ́n dáradára, ṣùgbọ́n wọ́n nílò à ti tún ìlú ara wọn ṣe!

Ọ̀RỌ̀ TÍ ÀÀRẸ TÓ NDÚRÓ LÁTI GORÍ ÀLÉÉFA NÍ AMẸ́RÍKÀ, èyíinì, Donald Trump, ọ̀rọ̀ tí ó sọ nìyí o, fún gbogbo àwọn tí ó wá láti òkèèrè sí Amẹ́ríkà, tí wọn ò sì ní ìwé ìgbélu tí ó péye dání. Ó ní, ẹ padà sílé yín!

Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá gbogbo (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), tí Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tí ó wà ní ìlú Amẹ́ríkà, àti káàkiri àgbáyé, ẹ máa bọ̀ nílé. Àmọ̀ràn ni o! Gbogbo èyí tí a nṣe ní Àjò, ó ti tó gẹ́ẹ́!

Ẹ jẹ́ kí á wá tún orílẹ̀-èdè wa ṣe, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y). Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y) ti dá dúró! A ti kúrò ní ara Nàìjíríà.

Gbogbo àwọn nkan tí Olódùmarè fi jí-nkí wa lórí ilẹ̀ wa, ó tó wa-á jẹ, ó tó wa-á ṣe ayé wa. Tí a bá ti tún ilẹ̀ wa ṣe, àwọn ìlú òkèèrè yẹn gan-an ni wọ́n á má wá ra nkan lọ́wọ́ wa – àwọn nkan tí a nṣe lórí ilẹ̀ wa.

Ọlọ́run ṣe oore-nlá fún wa ní ilẹ̀ Yorùbá. Ẹ jẹ́ kí á máa bọ̀ nlé. A máa tún ilẹ̀ wa ṣe. Gbogbo àwọn nkan tí àwọn ìlú òkèèrè yẹn fí kọ́ ìlú tiwọn lọ́hun, ilẹ̀ Áfríkà wa níbí ni wọ́n ti ko-ò. Ojú ti là o! kí á yéé fi ara wa sábẹ́ ẹnikẹ́ni!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ṣé a ti wá ri, báyi, gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P ti D.R.Y), pé wọ́n ti nfi ọwọ́ júwe ilé wa fún wa! Ẹ máṣe jẹ́ kí ó di èyí ti wọ́n á fi ipá lé wá jàde. Bí ó ti lè wù kí àjèjì ó ti pẹ́ tó ní ibi tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè àjogúnbá tirẹ̀, ìjọ́ tí àwọn ti òkèèrè ọ̀ún bá ti júwe ilé fun, ó tán nìyẹn o!

Orílẹ̀-èdè ẹni, òun ni orílẹ̀-èdè ẹni! ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ (DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA, D.R.Y), òun ni tiwa.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó lo Màmá wa, Ìyá Ìran Yorùbá, Ìránṣẹ́-Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fún iṣẹ́ ìgbàlà Ìran Yorùbá.

A ò ní gbàgbé, láyé, ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, èyí tí a jáde kúrò nínú Nàìjíríà, pẹ̀lú ìkéde Òmìnira wa; nípa iṣẹ́-rere náà tí Ọlọ́run ti ọwọ́ Màmá wa ṣe; bẹ́ẹ̀ ni a ò lè gbàgbé ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí Olódùmarè lo Màmá wa, MOA, láti ṣe Ìpolongo Ìṣàkóso-Ara-Ẹni wa, gẹ́gẹ́bí Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso tiwa níjọ́ náà, pẹ̀lú ìbúra-wọlé fún Olórí-Ìṣàkóso Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́.

GBOGBO ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ (I.Y.P) ti D.R.Y, Ẹ MÁA BỌ̀ NÍ’LÉ.

Tí ọmọdé bá ńjẹ èèwọ̀ tí ẹnìkan ò bi í, bó pẹ́ bó yá, ohun tí ńbi’ni ò ní ṣàì bi’ni