Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìgbádùn tí yóò wà fún wa kò lóǹkà, àìríjẹ ti di ohun ìgbàgbé ní ilẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ tó dára ní a óò máa jẹ́, 

nítorí pé ìṣàkóso D.R.Y kò ní fàyè gba ayédèrú oúnjẹ GMO tàbí lílo èròjà tó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn.

Ètò ìrànwọ́ yóò wà fún àwọn àgbẹ̀ láti leè máa pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, nítorí pé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni Olódùmarè fún wa, aò nílò láti bá orílẹ̀ èdè kankan d’òwòpọ̀ kí a tó leè jẹun, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àwa ni yóò máa pèsè ohun tí a nílò, ohun tí a bá sì ń pèsè náà ni a óò máa lò.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá.