Kí Olódùmarè kí ó má jẹ̀ẹ́ kí a fi ọwọ́ ara wa se ara wa ò. Nínú ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí arábìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tucker Carlson tí ó sì ń ṣe àlàyé àwọn àìsàn tí ó ń sẹ́yọ látàrí àwọn nǹkan jíjẹ tí kò dára, àti àyíká tí ó léwu, pàápàá ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Arábìnrin náà ṣeé lálàyé wípé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí nínú ọmọ mẹ́rìndínlógójì a ó rí ọ̀kan nínú wọn tí ọpọlọ rẹ̀ kò pé tó yàtọ̀ sí ìgbà kan tí ó jẹ́ wípé nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọmọ ni a ó ti rí ọmọ kan ṣoṣo bẹ́ẹ̀.
Obìnrin náà ṣeé lálàyé wípé, ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lónìí, ìdá mẹ́rìnléláàdọ́rin àwọn àgbà ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún ni wọ́n ti sanra jù, àti idà àádọ́ta àwọn ọmọdé bákannáà.
Ìdá àádọ́ta àwọn àgbà ni wọ́n ti ń ní àrùn ìtọ̀ṣúgà, ìdá ọgbọ̀n sì ni ti àwọn ọ̀dọ́. Lọ́dọọdún ni iye àwọn tí ó ń ní ìpènijà ọmọ bíbí sì ń lé síi,bẹ́ẹ̀ sì ni iye àtọ̀ ara ọkùnrin ń dín kù pẹ̀lú ìdá kan lọ́dọọdún.
Ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rin àwọn ọ̀dọ́ ni ó sì ti ní àìsàn jẹjẹrẹ. Kíni ó wá ń ṣe okùnfà àwọn àìsàn yí? Ó ní àwọn oúnjẹ olóró ni, àti àyíká tí ó léwu.
Fún ìdí èyí, gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra fún ìjẹkújẹ, kí a má sì máa gba ohun tí ó léwu ní àyíká wa.
Sebí nígbà gbogbo náà ni a máa ń sọ fún wa wípé, àwọn nǹkan aláwọ̀ funfun tí a gbàgbọ́ pé ó dára jù lọ nì, àkóbá púpọ̀ ni ó ń ṣe ní àgọ́ ara wa.
Ìdí nìyí tí a fi ń sọ fún wa wípé, ẹ jẹ́ kí a máa gbé àwọn ohun tí ó jẹ́ tiwa lárugẹ. Gbogbo ohun tí Olódùmarè fún wa ní ilẹ̀ Yorùbá, dáradára ni ó ṣe wọ́n, tí kò sì ní ṣe ìjàǹbá fún wa ní àgọ́ ara wa.