Olórí ìṣàkóso-adelé Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, sọ ọ̀rọ̀ l’orí àwọn ànfààní ìgbáyégbádùn tí ó ti wà fún ṣíṣe’ṣẹ́ tọ̀, tí àwọn ìṣàkóso-adelé wa bá ti wọlé sínú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso ní gbogbo ìpínlẹ̀ wa méjèèje.
Wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yí lára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá gbogbo àwa ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá sọ, ní àjọ̀dún ọdún-kejì tí a ti di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira, látàrí ìkéde-òmìnira wa tí a ṣe ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, èyí tí àjọ̀dún kéjì rẹ̀ wáyé ní Ọjọ́’Rú, ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí.
Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ sọ pé gbogbo ayẹyẹ tí ó yẹ ká ṣe ní àjọ̀dún ọdún-kéjì yí, ni a máa ṣe papọ̀ pẹ̀lú àjọyọ̀ nígbàtí ìṣàkóso-adelé wa bá wọ inú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso wa gbogbo láìpẹ́; wọ́n ní kí a máa yọ̀ nítorí a ti dé ipele tó kẹ́yìn náà, àti pé Olódùmarè ti bá wa ṣẹ́gun àwọn tó ńjẹgàba sórí ilẹ̀ wa.
Wọ́n wá sọ pé, nígbà tí wọ́n bá ti wọlé sínú oríkò ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso, ni ṣíṣe’ṣẹ́ tọ àwọn ohun ìgbáyé-gbádùn kan á bẹ̀rẹ̀, kí gbogbo I.Y.P (ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá) ti D.R.Y ó lè máa jẹ ìgbádùn rẹ̀.
Lára àwọn ńkan tí wọ́n kà sílẹ̀ ni, Ètò ìwòsàn-ọ̀fẹ́ fún aláboyún, ọmọ-ọwọ́ àti arúgbó; Ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ láti ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ dé ìgboyè-àkọ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga-jùlọ; iṣẹ́ fún gbogbo agbaṣẹ́ṣe ní yanturu; ṣíṣí àwọn ibodè wa láti kó onjẹ wọlé.
Àwọn míràn ni, títì tó já geere; iná mọ̀nọ̀mọ́nọ́ tí kò ní ṣẹ́jú; omi-ẹ̀rọ tó mọ́ tótó; ètò tó múná-dóko lórí gbogbo ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ bíi ẹ̀ka ìṣòwò, ẹ̀ka ti ìṣúná-owó, ẹ̀ka ti ilé-ìfowópamọ́, ẹ̀ka ti gbogbo ilé-iṣẹ́ àwọn aṣojú-orílẹ̀-èdè D.R.Y, ẹ̀ka tí ó ńṣe alámojútó gbogbo ìpínlẹ̀ méjèèje D.R.Y.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n mẹ́nu ba àwọn ètò-ọ̀fẹ́ kan lórí owó-ibodè sísan fún ẹrù tí ọmọ I.Y.P bá gbé wọlé gba ẹnu-ibodè láti inú ọkọ̀-ojú-omi.