Tí a bá ti lé àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ wa kúrò tán, ní Àṣẹ Èdùmàrè, tí ìjọba-adelé wa ti wà ní ojúkò Ile-iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ wa k’ọ̀kan jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, àwa ọmọ D.R.Y kò lè nípa nínú ewu tí ó wà nínú ìjàmbá àwọn onjẹ aṣekú-pani.
Ní ìlú Amẹ́ríkà, àjọ tí ó nbojútó Onjẹ àtí Òògùn (FDA) ti gba àwọn tí ó nṣe ayédèrú onjẹ (GMO) láyè kí wọ́n sọ pé onjẹ gidi ni. Torí èyí, ó ṣòro láti dá onjẹ GMO mọ̀. Lórí ẹ̀rọ ayélujára, Instagram, ni a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yí.
Bẹ́ẹ̀ náà ni a gbọ́ pé àwọn kẹ́míkà kan tí wọ́n nlò láti fi tọ́jú onjẹ gidi, pàápàá, máa nṣe aburú fún ara.
Irúfẹ́ àwọn kẹ́míkà bẹ́ẹ̀ kìí kúrò l’ára bọ̀rọ̀, wọ́n sì lè dúró lára ènìyàn fún bí ọdún márùn, méje tàbí mẹwa, tí o si lè fa àrùn ọlọ́jọ́ pípẹ́ sára.
Àìsàn kò ní wọlé tọ̀ wá o. Kì ojú má ríbi, gbogbo ara loògùn rẹ̀. Gbàrà tí àwọn adelé wa bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò ní sí àyè fún irú ìwà aburú bẹ́ẹ̀.