Ọ̀dọ́ kó ipa pàtàkì láwùjọ, ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ wí pé, orílẹ̀ èdè kórílẹ̀ èdè tí kò bá fi ti ọ̀dọ́ ṣe, irú orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ máa parun ni nítorí pé ọ̀dọ́ ní agbára orílẹ̀ èdè.
Àwọn Yorùbá náà ni wọ́n máa ń paá lówe wípé òrìṣà tí aò bá fi mọ ojú ọmọ, irú òrìṣà bẹ́ẹ̀ yoo parun ni.
Ìdí nìyí tí màmá wa tí Olódùmarè rán sí wa ní àkókò yí, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fi máa ń sọ fún wa nígbà gbogbo pé àwọn ọ̀dọ́ ni yóò ṣe ìjọba ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, nítorí pé ògo pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ wa gidigidi.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ a gbọ́dọ̀ ní àfojúsùn bí a ṣe leè ní ipa rere ní àwùjọ wa, nítorí wípé, a ní agbára láti ṣẹ̀dá ọjọ́ iwájú rere fún ara wa àti fún ìran tí ńbọ̀.
A gbọ́dọ̀ máa gba àwọn ọ̀dọ́ akẹgbẹ́ wa níyànjú láti sa ipá wọn láti leè rí dájú pé wọ́n ní ìfẹ́ ìran wọn tọkàntọkàn, débi wípé kò ní sí ohunkóhun tí wọ́n kò ní leè ṣe fún ìran wọn láì bójú wẹ̀yìn.
Ojúṣe ọ̀dọ́ ni láti ṣe ìwádìí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ, tàbí ṣe ìwádìí ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ kí wọ́n sì máa lépa láti sọ ohun gbogbo di ọ̀tun ní àwùjọ.
Nítorí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa, ẹ má ṣe fi ara yín sílẹ̀ láti lò ní ìlòkulò lábẹ́ àwọn apanilẹ́kún jayé àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, èkíní ni pé, kò sí ohun rere kan tí àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà lè ṣe fún yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ bíkòse pé kí wọ́n máa rán yín nísẹ́ ikú kiri.
Èkejì ni wípé, àwa Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Fún ìdí èyí, gbogbo ẹ̀yin ọ̀dọ́ Ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, oríire wa tí dé, gbogbo ẹ̀yin ọ̀dọ́ tí ẹ ti jáde ilé ìwé tí kò sí iṣẹ́, ayọ̀ yín ti dé nítorí pé àgbékalẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ tí ó dára ti wà nílẹ̀ fún wa, iṣẹ́ yóò sì wà lọ́pọ̀ yanturu láti ṣe, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a f’ọwọ́sowọ́pọ̀ kí a sì ti àwọn adelé wa lẹ́yìn nígbàkúùgbà tí a bá ti gbọ́ ìpè wípé àkókò ti tó láti ṣe àjọyọ̀ náà, ilẹ̀ Yorùbá ti dúró!