Ìròhìn tó gbenu tán kan la rí lórí fọ̀rán kan nípa ọ̀dọ́ tó lo ọgbọ́n àrékérekè láti kó owó ninu àpò ilé ìfowópamọ́ bàbá kan ni nílùú Gbẹ̀rígbẹ̀, Ìkòròdú, ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílẹ-èdè D.R.Y.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Pín Sorí X

Gẹ́gẹ́bí ìròhìn náà, ọ̀dọ́mọkùnrin náà lọ bá bàbá kan pé kí ó jẹ́ kí òun ba ṣáàjì ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀, bàbà yí sí gbé le lọ́wọ́ láti lọ ba ṣáàjì, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin yí pàrọ̀ síìmù rẹ̀ kí ó tó dá ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ padà fun bàbá, láàrín wákàtí díẹ̀ ó tí fi síìmù baba yi wọ́ owó tí ó jẹ́ ọgọ́ta ẹgbẹ̀rún naira kúrò nínú àpò ilé ìfowópamọ́ bàbá sí òmíràn fún ara rẹ̀, o hùwà olè, ọ̀dájú àti ọ̀daràn.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Nítòótọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà hùwà burúkú, ṣùgbọ́n àwọn ìlú Naijiria mùjẹ̀mùjẹ̀ tó ṣì ńfi agídí jẹ gàba lórí Orile-ede wa D.R.Y. ló fa àwọn ìwa búburú tí àwọn ògo ọ̀la wa yìí ńhù, wọn kò ṣètò ẹ̀kọ̀ tó dára, bẹ́ẹ̀nií iṣẹ́ gidi kankan kò sí èyí ló mú kí àwọn ọ̀dọ́ rí àyè fún èrò àti ìwà tí kò dára rárá.

Láfikún, ti ìjọba Naijiria agbésùnmọ̀mí àti olè yí bá pèsè iná mọ̀nàmọ́ná ni, kò lè sí ìdí kankan láti máa lọ ṣáàjì ẹ̀rọ́ ìbánisọ̀rọ̀ kiri debi tí wọ́n ma fi síìmù kó ni lówó lọ́.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: Ìgbé-Ayé Tinubú – Ìgbé-Ayé Irọ́ Pátá Gbáà Ni

Orilẹ-ède Democratic Republic of the Yorùbá ní odò nlá tí a lè ti ṣe iná mọ̀nàmọ́ná tí kò ní máa ṣẹ́jú tí gbogbo àwọn ènìyàn máa lò tí a ó tún rí láti tà fún àwọn Orílẹ-èdè miran, ṣugbọn awọn ajẹgaba yí kò f’àyè gbà wá, la ṣe ń kìlọ̀ fún wọn kì wọ́n má báà kan ìdin nínú iyọ̀

Ìkìlọ rèé fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá pé kí a ṣọ́ra gidi pẹ̀lú síìmu wa kì a má bàá kábàmọ̀. A sì tún ńṣe ìkìlọ gidigidi fún ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria pẹlu gómìnà wọn Sanwoolu tí ń fi ipá jẹ̀gaba ní ìpínlè Èkó àti àwọn tó ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ wa pé kí wọ́n fi Orílẹ-èdè olómìnira tiwantiwa tí Yorùbá sílẹ̀ fún wa kí wọ́n gbọ̀nà Nàìjíríà lọ̀ ki a lè rí àyè tún ìlú wa ṣe bí ó ṣe dara fun igbadu ara wa.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: Ìjọba Naijiria Tó Ńfi Agídí Jẹ Gàba Lórí Ilẹ̀ D.R.Y Tẹ̀síwájú Láti Rú Òfin Àgbáyé

Ọjọ́ ìtìjú àti ìyá ńsúnmọ́ etílé fún àwọn ajẹgaba ilu afẹ̀mìṣòfò tó ńjẹ́ Naijiria tí wọ́n ń fi ògo àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá ṣòfò.