Àwọn àjọ tí wọ́n ń rí sí sísàkójọ, ṣíṣe àtúpalẹ̀ àti pípín statistiiki àti àwọn ohun tí ó jọmọ́ ọ̀rọ̀ àwùjọ, okòwò àti iṣẹ́ ṣíṣe ní àyíká ni wọ́n ti ṣíṣọ lójú eégún báyìí ó, tí wọ́n wí pé, ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń gbà sí iṣẹ́ ní Nàìjíríà ni wọ́n ń gbà nípa gbígba rìbá tàbí kí ẹni náà jẹ́ ìbátan tàbí kí ó jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀nà méjèèjì yìí láàárín ẹgbàá ọdún àti jókòó sí ẹgbàá ọdún àti lókòólémẹ́ta.
A rí ọ̀rọ̀ yí nínú èsì tí àwọn àjọ yí fi síta tí wọ́n sì pe àkọ́lẹ́ rẹ ní ‘’Ìwà ìbàjẹ́ ní ìlú Nàìjíríà’’, àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣeé àti sísọọ́ di àṣà. Ọ̀rọ̀ yí dá lóríi ìwádìí kan tí àwọn Ọ́fíìsì Àjọ Àgbáyé lórí Oògùn àti ìwà ọ̀daràn ṣe.
Èsì ìwádìí náà tún tẹ̀síwájú wípé, nínú ìdá ọgọ́ta yìí, ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni ó rí iṣẹ́ nípasẹ̀ rìbá sísan, ìdá mẹ́tàlá ní wọn gbà sí isẹ́ nípasẹ̀ jíjẹ́ ìbátan, tí ìdá mọ́kàndínlógún sì gba ípasẹ̀ ọ̀nà méjèèjì yìí rí isẹ́ náà.
Nínú ìwádìí ọ̀hún ni wọ́n ti wá ríi wípé, ìdá ogójì àwọn tí wọ́n ń rí iṣẹ́ náà ni wọ́n ń gba ọ̀nà tààrà wọlé láìjẹ́ wípé wọ́n san rìbá tàbí jẹ́ ìbátan wọ́n.
Ètò ìgbanisísẹ́ kó ipa pàtàkì púpọ̀ láti tún àṣà ij’ọ́mọlúàbí ènìyàn ṣe àti láti ríi dájú wípé àwọn tí wọ́n ń gbà sí iṣẹ́ kún ojú òṣùwọ̀n.
Nípasẹ́ ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ẹgbàá ọdún àti okòólémẹ́ta, ni wọ́n ti ríi wípé, ètò ìgbanisísẹ́ nílò àmójútó gidigidi látàrí bí ó ti jẹ́ wí pé ìdá mẹ́rìndínládọ́ta àwọn tí wọ́n rí isẹ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ní wọn san rìbá, tí ìdá méjìlélọ́gbọ̀n sì ti ipasẹ̀ ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan rí iṣẹ́ náà.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwádìí tí wọ́n ṣe ní bíi ọdún mẹ́ta ṣáájú ẹgbàá ọdún àti okòólémẹ́ta fi ìdí rẹ múlẹ̀ wípé, ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń gbà sì ‘ṣẹ́ ni wọ́n ń gbà nípasẹ̀ rìbá àti jíjẹ́ ìbátan wọn.
Irú àwọn ìwà àjẹbánu bá wọ̀nyí ni a ó ní gbà láàyè lórí ilẹ̀ wá Democratic Republic of the Yorùbá, nítorí wípé àparò kan kò ní ga jù kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Iṣẹ́ pọ̀ yanturu ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira tiwantiwa tí Yorùbá, kò sí pé tí ò bá mọ́ yàn ó lè rì ṣẹ́.