Àjọ tí ó ń ṣe àmójútó àwọn àìsàn pàjáwìrì ní orílẹ̀-èdè afẹ̀mísòfò Nàìjíríà, ni ó gbé ìkéde síta nínú ìròyìn kan lórí ọ̀rọ̀ MPOX ní ọgbọnjọ́ oṣù Ògún ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún wípé, àwọn ti ní ènìyàn méjì dín làádọ́ta ní Àbújá, tí íṣe olú ìlú mùjẹ̀mùjẹ̀ Nàìjíríà, Eko (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), Rivers àti àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta dín lógún, tí àìsàn MPOX náà tí ń bá jà.
A ò sọ wípé kò sì òtítọ́ nínú ìròyìn yí, nítorí àwọn àjọ náà ni ó gbée jáde, kì í ṣe ẹnìkan ló sọ ọ ṣùgbọ́n, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé, lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí tí àwọn ajẹ gàba kò tíì kúrò ni oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa ní ìpínlẹ̀ méjèèje tí orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá(D.R.Y), ìyẹn ni pé, a kò tíì yọ èpò kúrò nínú àlìkámà,ẹ jẹ́ kí á kíyesará, àwa ọmọ Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), kí àjàkálẹ̀ àrùn náà má báà gb’ilẹ̀ ju bí a ti ṣe gbọ́ ọ yí lọ ní órílẹ̀-èdè D.R.Y.
A ní láti ṣọ́ra gidi kí ìlú apaná ògo Nàìjíríà má kó tiẹ̀ bá wa; bẹ́ẹ̀ ni ìròyìn náà sọ pé wọ́n rí ẹnikan ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, àti ẹni méjì ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun,ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ẹ jẹ́ kí á ránti COVID 19, ebola, àti HIV; ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù tì wá lọ ṣe ohunkóhun lòdì sí ohun tí ìjọba Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) bá sọ nítorí, ìròyìn náà sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wa abẹ́rẹ́-àjẹsára mpox ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjìríà ti gbà wọlé láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Olódùmarè á máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa, títí a ó fi rẹ́yìn àwọn asíwín ìjọba Nàìjíríà.
Ẹ jẹ́ kí á máa ṣe ìmọ́tótó ara, aṣọ, oúnjẹ àti àyíká wa nígbà gbogbo. Kí àwọn èwé àti egbò tí ó le ràn wá lọ́wọ́ wà ní àrọ́wọ́tó wa bákanáà.
Kí á yàgò fún abẹ́rẹ́-àjẹsára tàbí oògùn tí ìjọba orilẹ̀-èdè wa D.R.Y, kò lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
Ẹ ránti pé, a ti kúrò nínú ìlú òṣì Nàìjíríà; ìjẹgàba wọn ló ṣ’okùnfà irú ìròyìn báyi bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí èyí tó kàn wá nínú ìlú amúnisìn wọn. Kí a máṣe gbára lé ọ̀tá wa, ìlú apànìyàn ní Nàìjíríà.