Ọ̀rọ̀ akin ati ìgboyà yí ló jáde láti ọ̀dọ̀ olórí Orílẹ̀ èdè Burkina Faso, Ọ̀gágun Ibrahim Traore, akíkanjú ọ̀dọ̀mọkùnrin tó fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ tọkàn- tọkàn.
Ọ̀rọ̀ akin náà jẹ́ eyi tí aṣojú Ọ̀gágun náà ṣe àgbékalè rẹ ni iwájú àwọn ìjọba àgbáyé (UN) ni ìlú New York. Àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ sí ìjọba àgbáyé dá lé lórí: ìwà àgàbàgebè, ìmúni’lẹ́rú, ìjẹgaba, àìṣòdodo, ìninilára, ole àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, tí àwọn aláwọ̀ funfun ń hù sì àwa alọ̀wọ̀ dúdú, ó ní, ìwà burúkú gbáà ni.
Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ Ààrẹ àti olórí ìjọba Áfríkà kò ní ìgboyà láti sọ irú òtítọ́ yìí nítorí wọn ò lè kojú àwọn òyìnbó amùnisìn, ìwà àgàbàgebè ní wọ́n fí ń ṣe ìjọba.
Traore tún rán agbẹnusọ rẹ̀ pé nítorí náà, àwọn tí jáde kúrò nínú ìjẹgaba òyìnbó Faransé, láì sí ìbòjú wẹ̀yìn.
Báwo ni eléyìí ṣe kan àwa Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y)? Èyí rán wa létí ọ̀rọ̀ tí màmá wá Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìírí-Abíọ́lá (MOA) tẹnu mọ́, wípé àwọn ọ̀dọ̀ ló ma ṣe ìjọba ni Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Nítorí Olódùmarè fún wọn ní ọgbọ́n àti imọ.
Fún àpẹẹrẹ, láti ìgbà tí lbrahim Traore tí bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba ni ìtẹ̀sìwájú tí dé bá àwọn ará ìlú Burkina Faso lóríṣiríṣi ọna. Nítorípé ó jẹ́ ọdọ tó ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ní ìran tó lógo fún orílẹ̀ èdè rẹ.
Àwa dupẹ lọ́wọ́ màmá wa alálùbáríkà tí wọ́n gbà láti jẹ́ ohun èlò lọ́wọ́ Olódùmarè fún iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Aládé, a dúpẹ̀ bákannáà lọ́wọ́ olórí ìjọba Adelé wa, bàbà wá Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ àti àwọn Adelé wa t’ókù tí wọ́n gbà láti ṣiṣẹ́ sin Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y). Wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ isẹ ni pẹrẹu láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún. Kò si ìbòjú wẹ̀yìn mọ́, Ó ti tan fún ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà.