Kíni à bá fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àṣeyọrí jíjáde tí a ti jáde kúrò nínú aríremáse nàìjíríà, nípasẹ̀ iṣẹ́ tó gbé lé Màmá wa lọ́wọ́: Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.
Ìdí ọpẹ́ wa ni pé, ṣé bí àwa náà ìbá ti máa yí láti inú gbèsè kan sí òmíràn nìyí?
Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ lórí ayélujára sọ pé bílíọ̀nù kan-àbọ̀, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọrin dọ́là ni gbèsè tí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tó ń fi agídí dúró sórí ilẹ̀ wa D.R.Y, tún ti yá lọ́wọ́ ìlé-ìfowó-pamọ́ àgbáyé,gbèsè ń yí lu gbèsè fún wọn níbẹ̀.
Ṣé èyí kò tilẹ̀ kàn wá tí kò bá ṣe ti ipá tí wọ́n fi dúró lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y). A ti ṣe ìkéde òmìnira wa, ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni ní ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún, nítorí èyí, gbèsè yòówù tí ajẹgàba Nàìjíríà ìbáà jẹ, kò kàn wá.
Gẹ́gẹ́bí ìròyìn náà ṣe sọ, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù dọ́là yóò wà fún “ọ̀rọ̀-ìṣèjọba tí ó fa ìlọsẹ́yìn fún ètò ẹ̀kọ́ àti ti ìlera.” Àwa ò mọ ìtúmọ̀ gbólóhùn gbọọrọgbọ yí, ìgbà tí wọ́n bá ti fẹ́ kó’wó jẹ ni wọ́n máa ń sọ àwọn òyìnbó òfò tí kò ní ìtumọ̀.
Ṣùgbọ́n ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin dọ́là míràn wà fún ètò ìwòsàn fún àwọn obìnrin, ọmọdé àti ọmọ tí kò kọjá ọdún mẹ́tàlá, tí a bá lọ tí a bá bọ̀, ibi kan máa wà tí ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́-àjẹsára máa jẹyọ.
Fún ìdí èyí, kí àwa I.Y.P ó ṣọ́ra dáadáa, nítorí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé náà ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń dojú-kọ. Ohun tí ó bá ti yàtọ̀ sí ohun tí Ìjọba-Adelé wa bá sọ, kí a máṣe lọ́wọ́ síi.