Ètò ìṣèlú ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kò ní fí àyè gba àjèjì láti díje fún ìpò kankan nínú ìdìbò orílẹ̀ èdè Yorùbá. Màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ lára àlàyé wọn nípa ètò ìdìbò wa, bí ó ti wà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ fún ìran ọmọ Aládé.

Màmá wa MOA tan ìmọ́lẹ̀ síwájú síi pé ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) nìkan ló ní ẹ̀tọ̀ láti ṣ’ojú ọmọ Yorùbá ní gbogbo ipò ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa àti pé àwa ọmọ Aládé kò gbọdọ̀ tún gbé ìṣàkóso wa lé àtọ̀húnrìnwá lọ́wọ́, a kò ní padà sí oko ẹrú míràn láéláé.

Ìrírí wa nínú oko ẹrú àwọn òyìnbó amúnisìn àti ìrìn-àjò wa nínú àsopọ̀ tipátipá pẹ̀lú agbésùmọ̀mí nàìjíríà kìí ṣe ohun tí ó dára, bẹ́ẹ̀ni kò so eso rere fún wa, ṣe ní ó fa ìfàsẹ́yìn àti aburú fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá. Nítorínáà a níláti kíyèsára gidi kí a má tún padà já sí kòtò. 

Ní déédé ìgbà yìí àti ní déédé àsìkò yí tí Olódùmarè ti lo ìránṣẹ́ Rẹ̀ màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti kó àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kúrò nínú àsopọ̀ agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà láì sí ogun tàbí ìtàjẹ̀sílẹ̀, nípa ìkéde òmìnira wa kúrò nínú àsopọ̀ búburú náà ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún, tí a sì búra wọlé fún olórí Alákòóso orílẹ̀ èdè wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa láti ìgbà náà lọ, a kò gbọdọ̀ fi àyè sílẹ̀ fún àjèjì láti rápálá wọ’nú ìṣàkóso wa. Ìdí nì yí tí a níláti ṣọra kí omí má bàá tí ẹ̀yìn wọ̀ ìgbín wa lẹ́nu.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates