Fọ́nrán kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára ṣe’ni láàánú, kódà ó gba pé kí ènìyàn má le wòó: ní’bi tí obìnrin kan ti gbé òkèlè ní ọwọ́ kan, tí ó sì lóṣòó ti omi-ìdọ̀tí nílẹ̀, tí ó ń fi ọwọ́ kéjì bu oúnjẹ yí, tí omi-ìdọ̀tí yẹn wá jẹ́ ọbẹ̀ tí ó fi ń jẹ oúnjẹ ọ̀ún! Háà.
Ẹ̀yin ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á ronú wa dáradára: ọjọ́ mélòó la ṣì tún fẹ́ máa rí ìríkúri yí? Kí ọmọ ènìyàn máa fi omi-ìdọ̀tí, tí ó dágún, kí ó máa fi ṣe ọbẹ̀!
Ìbáà ṣe wèrè; ṣebí tí ìlú bá dára, wèrè gan-an á mọ̀ọ́ lára: gbogbo ìlú agbésùnmọ̀mí tí a ti kúrò yí, ti ya wèrè, wèrè olóṣèlú, wèrè ààrẹ, wèrè ọlọ́pàá, wèrè ológun, wèrè adájọ́; wèrè ìlú: ẹ jọ̀ọ́, gbogbo àwọn tó bá ń gbọ́ wa, tí ìròyìn yí dé ọ̀dọ̀ yín; ṣùgbọ́n tí bó ṣe ń lọ kò tíì yée yín, ẹ jẹ́ kó yée yín o!
Òkú-ìlú pátápátá gbáà ni ìlú tí wọ́n ń pe’ra wọn ní Òmìrán Áfríkà o! Kò sí òmìrán kankan níbẹ̀, àfi òmìrán òṣì àti ìṣẹ́; òmìrán àìr’ógolò; òmìrán-àìríjẹ; òmìrán-àìrímu, òmìrán àìríṣe; òmìrán àìláṣeyọrí!
Olóṣèlú akótilétà Nàìjíríà burú jáì! Ẹni tí ó bá ṣì ń rò pé ìrètí wa fún ìlú wèrè yí, á jẹ́ pé àrùn kan-náà ló ń ṣe àt’òun àti ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjírà!
Ọmọ Yorùbá, àwa tí a súnmọ́ àwọn tí kò tíì ri pé ọkọ̀ ìparun ni ìlú wèrè yẹn jẹ́, ẹ jẹ́ ká fi tó wọn létí, bí wọ́n bá ṣìlè gbọ́: kí ọmọ Yorùbá kankan máṣe tẹ̀lé olóṣèlú ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà mọ́.
Àwa ò kìí ṣe Nàìjíríà ìlú aríremáse mọ́: kí a jẹ́ kí gbogbo ẹni tó nílò àti gbọ́, kí wọ́n gbọ́: ọmọ Yorùbá, Nàìjíríà ìlú àwọn ajẹgàba kò ro ire sí yín, rárá! Irú ohun tí a rí nínú fọ́nrán yí, láyé, kò ní ṣẹlẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gbogbo wa ni a máa jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù.