Ní Orílẹ̀-Èdè Olóminira Tiwantiwa ti Yorùbá, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, máa nsọ fún wa pé ìtọ́jú tó péye máa wà fún gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, látàrí bí ìlú ṣe máa dára tó, bíó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ṣe iṣẹ́ tọ̀ọ́ ni, ṣùgbọ́n fún àwọn arúgbó wa, ìjọba tún ní ètò bí ọjọ́ ogbó wọn ṣe máa dára, èyí tí ó jẹ́ pé, àwọn àlejò ní ìlú wa yíò máa bérè pé ṣé kò sí arúgbó ní ìlú wa ni? – tí a dẹ̀ máa dá wọn lóhùn pé ìkan rèé níwájú yín, ọmọ ọgọ́run ọdún ni!

Èyí fi hàn wá pé, bẹ̀rẹ̀ láti bí ìlú wa ṣe máa dára tó, nígbà tí ìjọba wa bá ti wọlé sí oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, pẹ̀lú ìtọ́jú tí a máa tún fún àwọn arúgbó láti ri pé ọjọ́ ogbó wọn dára, nípa ti ètò ìwòsàn, sísan owó ìfẹ̀hìntì fún àwọn tí ó ti jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba nínú wọn, ìbalẹ̀-ọkàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ìgbádùn ni ó máa wà fún arúgbó wa, yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọmọ tiwọn pàápàá máa lè ṣe fún wọn látàrí bí ìlú ṣe máa dára tó.

Nítorí èyí, ọjọ́ ogbó tó dára, láṣẹ Èdùmàrè, wà fún gbogbo àgbàlagbà àti arúgbó wa ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

Ká Ìròyìn Síwájú sí: