Oríṣiríṣi nkan ni a ti gbọ́ nípa bí àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe fẹ́ kó aláwọ̀dúdú kúrò nílẹ̀, kí wọ́n lè gba ilẹ̀ wa, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ra; àti kí àlùmọ́nì ilẹ̀ wa ó lè di tiwọn pátápátá láìsí àtakò kankan.
Ṣùgbọ́n, kìí wá nṣe èyí nìkan ni àwọn òyínbó wọ̀nyí nwá o! Paríparì rẹ̀ ni pé, àwọn òyìnbó wọ̀nyí njowú irú-ìṣẹ̀dá tí Olódùmarè ṣẹ̀dá aláwọ̀dúdú, tí ó jẹ́ pé ìṣẹ̀dá wa ló lágbára jù, tí ó sì ní Ògo jù ní gbogbo àgbáyé!
Gbòógì nínú ìdí nìyẹn tí wọ́n fi nwá ẹ̀yà-ara aláwọ̀dúdú, kí wọ́n le ṣe Ẹ̀dà rẹ̀ láti inú iyàrá sáyẹ́nsì tiwọn: èyí tí ó túmọ̀ sí pé, kí ó má ṣe sí ènìyàn dúdú mọ́ ní àgbáyé, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ òyìnbó nísiìyí ni wọ́n á wá ní irúfẹ́ agbára àti Ògo tí ènìyàn dúdú ní.
Ọkùnrin ará ìlú Kenya kan tí ó sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára YouTube, lórí nkan wọ̀nyí, sọ pé Ẹlẹ́da kò le gbà kí èrò àwọn amúnisìn òyínbó wọ̀nyí kí ó ṣẹ-ẹ̀, nítorí ti Èdùmàrè ló máa lékè ṣáá ni.
Àwa gẹ́gẹ́bí Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), níláti mọ̀ pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣírí ni ó ṣì máa tú, ṣùgbọ́n, lágbára Olódùmarè, kí àwọn agbésùnmọ̀mí ìlú wèrè, Nàìjíríà, ó kúrò lórí ilẹ̀ wa ná, kí ìjọba wa, ìjọba Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ó wọlé sínú àwọn oríkò-ilé-iṣẹ́-ìjọba wa gbogbo káàkiri Orílẹ̀-Èdè wa, nígbànáà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oríṣiríṣi nkan máa wáyé – ní ìdàgbàsókè ọlọ́kan-ò-jọ̀kan, àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí ojú wa ṣì máa ṣí sí, fún òtítọ́ láti lékè, kí Ìran Yorùbá ó wà ní ṣíṣe Ìpò tí Olódùmarè ti fi wá sí.