Láìpẹ́ yí ni a mú ìròhìn tó wa létí bí wèrè ọkùnrin kò jẹ́ Íbò kò jẹ́ Bìní kan ṣe npè fún ogun, pé kí àwọn Ibò tó wà ní Èkó ó dojú ìjà kọ’ra wọn láìṣe àwa.
Ìròhìn tí a tún rí lórí ẹ̀rọ ayélujára X, fi hàn pé ọmọ-ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ẹgbẹ́ ààrẹ wọn ní Nàìjíríà lọ́hun ni ọkùnrin náà. Wọ́n tún sọ pé ó nṣiṣẹ́ fún ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, èyí tí ó njẹgàba lórí Ìpínlẹ̀ Èkó wa, Democratic Republic of the Yoruba.
Ìṣèjọba-ara-ẹni Democratic Republic of the Yoruba, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ni ìpìlẹ̀ tí Olódùmarè fún wa; kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le ṣe ohunkóhun lòdì sí èyí.
Kí gbogbo olùgbé Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ó tẹ̀lé òfin Orílẹ̀-Èdẹ wa. Ẹni tí òfin wa bá gbà láyè láti dúró sórí ilẹ̀ wa, níláti tẹ̀lé Òfin wa tàbí kí ó fi ilẹ̀ wa sílẹ̀.