Ìyàlẹ́nu ń lá ló jẹ́ láti rí ìròyìn kan lórí ẹ̀rọ ayélujára wí pé, ìjọba Bìrìtìkó (Gẹ̀ẹ́sì) gba àwọn nọ́ọ̀sì agbanipa ní àkókò àìsàn Covid 19 tó gba’lé gba oko nígbà náà láti pa ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gba ìtọ́jú fún àrùn náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù àwọn aláìsàn Covid 19 yí ni wọ́n pa láì jẹ́ kí àwọn ẹbí wọn ó mọ̀. Ìròyìn yí sọ pé òṣìṣẹ́ nọ́ọ̀sì kan nílé ìwòsàn ọ̀hún tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò dùn mọ nínú ni ó yọ́ ọ sọ sí’ta.
Ohun tí ó ya ènìyàn lẹ́nu ni pé, àwọn nọ́ọ̀sì agbanipa wọ̀nyí ò lo àmì ìdánimọ̀ kankan, wọ́n sì ti sá lọ, tí ẹnikẹ́ni kò lè sọ bí wọ́n ṣe leè rí wọn mú. Èyí tó fi hàn pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì mọ̀ nípa iṣẹ́ búburú yii.
Ṣé a tí wá rí ìdí tí màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá fi ń sọ fún àwa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P.), pé àwọn egbòogi ìbílẹ̀ wa ni a máa lò jù ni Orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), gbogbo òògùn òyìnbó tó bá fẹ́ wọ orílẹ̀ èdè wa ní a ó ṣe ayẹ̀wọ̀ wọn fínífíní kó tó wọlé kí ó sì tó di lílò fún àwọn ènìyàn wa.
Àwa ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí àwa fúnra wa kíyèsára, kí a má fi ọwọ ara wa fa wàhálà àwọn apanilẹ́kún j’ayé sí orí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), nítorí èèrà kò fẹ́ pòròpórò dé’nú ní àwọn aláwọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀nyí.
Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa ṣe pàtàkì ní àkókò yí àti nígbàtí wọ́n bá ti wọ oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa láì pẹ́ yìí, kí a lè tètè máa jẹ ìgbádùn ògo tí Olódùmarè tí ṣ’ètò fún wa nípasẹ̀ ìyá alálùbáríkà, màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla. Ayọ̀ wa tí wọlé báyìí.