Ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, ní agbègbè Amúlóko, ní Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba, ni ọwọ́ ti tẹ ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Musa tí ó sì ti ń kà bòòròbò báyìí látàrí pé wọ́n ká orí ènìyàn mọ́ọ lọ́wọ́.
Gégébí àlàyé ọkùnrin náà nígbàtí ó ń jẹ́wọ́ ìwà búburú yìí, ó ní ìgbà kejì nìyí tí òun yóò gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, kò tíì ju oṣù méjì péré tí òun bẹ̀rẹ̀ ìwà búburú náà, o sì fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀rẹ́ òun kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tunde ni ó máa ń gbé orí náà lọ fún àwọn tí yóò lòó, òun kò sì mọ ibẹ̀ rárá.
Ṣèbí gbogbo irú ìṣẹ̀lẹ̀ ìbaninínújẹ́ bí eléyìí ìbá má ti ṣẹlẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n nítorí àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ṣì ń fi ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ní.
Ojoójúmọ́ bayii ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò ṣeé gbọ́ sétí ń ṣẹlẹ̀ ní Orílẹ̀ Èdè Yorùbá, ọ̀rọ̀ náà ti wá le débi pé kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti ní owó nígbà tí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní olóṣèlú wọ́n kò sì bìkítà rárá.
Wọ́n ti sọ púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Yorùbá di ọ̀dájú, apànìyàn àti alágbe, tí kò sì sí irú eléyìí tẹ́lẹ̀ ní ìran Yorùbá.
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè pé ó ti gbà wá, tí a sì ti kúrò lára ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún nípasẹ̀ màmá wa tí Olódùmarè rán sí wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wá.
Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a ní sùúrù, ìgbà díẹ̀ ló kù, ẹ má ṣe hu ìwà ìpànìyàn tàbí wá owó lọ́nà àìtọ́ mọ́, ìṣẹ́ àti ìyà ti dópin nínú ayé wa, ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo tí ó kù náà ni kí àwọn tí ó ń fi ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa kúrò kí àwọn adelé wa sì wọ ilé iṣẹ́ ìjọba wa láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe fún wa, èyí kò sì pẹ́ mọ́ rárá, a ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ìgbádùn ìsèjọba tuntun tí yóò mú ìrọ̀rùn bá gbogbo wa nílé lóko.