Fọ́nrán kan ni a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí àwọn olùgbé Akinọla Aboru ti ń fi ẹ̀hónú hàn pé ètò iná mọ̀nà-mọ́ná tí Ìkẹjà Electric lò pẹ̀lú àwọn kò báwọn lára mu.
Àwọn ará àgbègbè náà ṣàlàyé pé, ipele Band A tí wọ́n gbé àwọn sí kò sàǹfàní kankan, ó kàn dàbí ẹni pé àwọn kàn ń san owó iná tí àwọn ò lò ni.
Ìjẹgàba nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa ló sì ń fa irú ìrírí báyìí fún ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P).
Tó bá jẹ́ pé aríremáse Nàìjíríà ti kúrò lórí ilẹ̀ wa láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní, ètò tó wà nílẹ̀ fún iná mọ̀nà-mọ́ná à bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í lòó.
A fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa MOA, fún ìtúsílẹ̀ àwa ìran Yorùbá kúrò lóko ẹrú, àwa ọmọ-ọkọ ìran aládé mọ̀-ọ́ ni oore o.
Nítorí náà, ẹ̀yin tí ẹ pe’ra yín ní gómìnà, tí kìí ṣe gómìnà D.R.Y, ṣùgbọ́n tí ẹ fi agídí dúró sí ilé-iṣẹ́ ìjọba ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), a ń sọ fún yín pé kí ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) kíákíá.