Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), gẹ́gẹ́bí Ìyá wa Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, ìwòsàn ọ̀fẹ́ wà fún ojúlówó Ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), lóòrè-kóòrè.
Àrùn-ọpọlọ èyí tí ó nmú ènìyàn ṣe àrìn-kiri ojú pópó ni D.R.Y kò ní gbà láàyè. Àkọ́kọ́, ọmọ aládé kò ní máa rìn-gboro kiri láì ní ìtọ́jú.
Èkéjì, orílẹ̀-èdè wa ní ètò tí ó yanran-ntí láti rí pé àjòjì tó bá wá sí ilẹ̀ D.R.Y kò ní jẹ́ alárín kiri tàbí ẹni tó máa di bùkátà s’ọ́rùn D.R.Y.
Nínú ohun gbogbo, ẹ jẹ́ kí á rántí pé Indigenous Yorùbá People (I.Y.P) ni ẹyin-lójú orílẹ̀-èdè wa.
Bí a ṣe máà mọ I.Y.P, ìyẹn wà ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tí Olódùmarè yọ̀nda fún D.R.Y, pàápàá ní títẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Ó gbé fún wa, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.