Ní agbègbè kan ní Manchester, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, obìnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì, tí àwọn kan júwe gẹ́gẹ́bí ọmọ Orílẹ̀ èdè Uganda, ni ó ṣe àgbákò ikú òjijì láti ọwọ́ ọmọ bíbí inú rẹ̀ èyí tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ogún ọdún lọ.
ìròyìn ọ̀hún tún tẹ̀síwájú wípé, lẹ́yìn tí ọ̀dọ́mọkùnrin yí gún ìyá rẹ̀ pa tán, ni ó tún lọ gún ọmọbìnrin míràn, ẹni ọdún mẹ́tadínlógún tí ó sì wà ní ẹsẹ̀ kan ayé àti ẹsẹ̀ kan ọ̀run báyìí.
Ọ̀dọ́mọkùnrin yí kò mà dá’wọ́ dúró níbẹ̀, ńṣe ló tún kọjá lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́rin-lé-lọ́gọ́ta tó sì gún un bákan náà. Ẹdà kéjì ìròyìn náà sọ pé bábá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ ni àwọn méjì tí ó tún gún lọ́bẹ yẹn.
Gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), tí a wà ní ìlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra gidi ní àkókò yí; oríṣiríṣi ń kan ló ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyi tó gba ìkíyèsára.
Bẹ́ẹ̀ ni kí á ṣe ojúṣe òbí fún àwọn ọmọ wa; kì ń ṣe ní pa fífún wọn lówó nìkan, ṣùgbọ́n kíkọ́ wọn lẹ́kọ ọmọlúàbí, nítorí ìlú tí wọ́n wà kò rọrùn.
Parí gbogbo rẹ̀, ẹ jẹ́ kí á rántí ọ̀rọ̀ olórí-ìjọba-Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, tí wọ́n sọ fún wa wípé àsìkò tó kí á máà bọ̀ ní orísun wa!